Koko iroyin: Ọ̀pá àṣẹ jíjígbé n'ílé aṣòfin, Igí wó pa akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà ni Cameroon

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

Wàhálà ilé aṣòfin àgbà; Ọ̀pá àṣẹ jíjígbé kiìí ṣe tuntun

Oríṣun àwòrán, @SenateNG

Àkọlé àwòrán,

Lásíkò tí ìjókòó ilé ń lọ lọ́wọ́, lawọn jàǹdùkùú ya wọnú ilé, tí wọn sì gbé ọ̀pá àsẹ ilé.

Awọn jàǹdùkú yabo ilé asòfin àgbà ní ìlú Àbújá, lásíkò tí ìjókòó ilé ń lọ lọ́wọ́, lawọn jàǹdùkùú yìí ya wọnú ilé, tí wọn sì gbé ọ̀pá àsẹ ilé.

Àtẹ̀jáde kan tí ilé asòfin àgbà ilẹ̀ fi síta lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà sàlàyé pé àwọn jàǹdùkú kan yabo àwọn níbi jókòó ilé, tí asòfin kan tí wọ́n ti ní kó lọ rọọ́kún nílé ná, Ovie Omo-Agege sì ló kó sòdí, tí wọn sì gbé lọ

Ìsẹ̀lẹ̀ Cameroon: Igí wó pa akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ilé ìwé àádọ́ta àti olùkọ́ mẹ́fà ni o lọ sí ìrìn àjò ẹ̀kọ́ náà.

Igi ti wó pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Naijiria mẹ́ta, ti mẹ́rìndínlógún si ṣèṣe lorílẹ̀èdè Cameroon nigbatí wọ́n kúro ní Nàìjíríà láti lọ wo àwọn ẹranko oríṣiríṣi lorileede Cameroon.

Alàkóso agbègbè náà wípé igi náà wo lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́yin ìji líle. E ka ekunrere re ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Ẹlẹ́wọ̀n: Ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ọmọdé ló gbé dé mi dé ẹ̀wọ̀n

Àkọlé fídíò,

Ẹlẹ́wọ̀n: Ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ọmọdé ló gbé dé mi dé ẹ̀wọ̀n