Wàhálà ilé aṣòfin: Àwọn ọlọ́pàá ti rí ọ̀pá àṣẹ padà

Ọ̀pá àṣẹ ati awọ̀n iwe ofin Image copyright NGR Senate
Àkọlé àwòrán Àwọn ọlọ́pàá ti rí ọ̀pá àṣẹ ilé aṣòfin padà

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá lórílẹ̀èdè Nàìjíríà ti kéde rẹ̀ pé àwọn ti rí ọ̀pá àṣẹ ilé aṣòfin tí àwọn jàǹdùkú kan wọ ilé gbé lọ ní ọjọ́rú.

Àwọn jàǹdùkú náà gbé ọ̀pá àṣẹ ilé aṣòfin ọ̀hún jù sílẹ̀ lábẹ́ẹ afárá ọkọ̀ tó wà lẹ́nu ìloro ìlú Àbúja.

Nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta, iléeṣẹ́ ọlọ́pàá olú-ìlú orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Àbúja ní kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni ikọ̀ kògbérégbè iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kán lu agbami iṣẹ ́láti ṣàwárí ọ̀pá àṣẹ náà.

Ṣáájú rírí ọ̀pá àṣẹ ilé aṣòfin àgbà yìí ni àwọn ọlọ́pàá ti fi panpẹ́ òfin mú Sẹ́nétọ̀ Ovie Omo-Agege tí ọ̀pọ̀ funrasí pé òun ló wà nídìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sùgbọ́n wọ́n ti dá a sílẹ̀ padà. Lẹ́yìn èyí ni àwọn aṣòfin àgbà tí fún wọn ní gbèdéke ọjọ́ kan láti wá ọ̀pá àṣẹ náà jáde.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: