Iléeṣẹ́ ọmọogun sáwọn olóṣèlú: Ẹ má t'ọwọ́ òṣèlú b'ọ̀rọ̀ ológun mọ́

Àwọn ọmọogun duro ya fọto Image copyright Nigeria Army
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ nǹkan ìjà olóró ati afunrasí ni àwọn ọmọogun ti gbà

Iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà ti ké sáwọn olóṣèlú láti yéé ti owọ́ òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun mọ́.

Iléeṣẹ́ ọmọogun ní àwọn ọmọ ogun ń ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́, ṣùgbọ́n adìyẹ rẹ̀ tóń làágùn, ìyẹ́ ara rẹ̀ ni kò jẹ́ kí a mọ̀.

Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú àwọn oníròyìn, ó ní, gẹ́gẹ́ bíi ara ìlàkàkà rẹ̀, àwọn jàǹdukú mẹ́tàlélọ́gọ́sán ni ọwọ́ ti bà lábẹ́ ètò kògbéégbè operation AYEM AKPATUMA.

Image copyright Nigeria Army
Àkọlé àwòrán Ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ yìí níí ṣe pẹ̀lú ìpè tí àwọn aṣòfin pè fún ìyọkúrònípò àwọn aṣíwájú ẹ̀ka iléeṣẹ́ ológun

Mẹ́tàdínláàdọ́ta nínú wọn ló jẹ́ afunrasí darandaran Fúlàní, mẹ́fà jẹ́ ẹlẹ́gbẹ́ òkûnkùn, máàrún jẹ́ ajẹ́rangbé tí mẹ́fà míràn sì jẹ́ agbébọn.

Bákannáà ni o tún ṣàlàyé rẹ̀ pé onírúurú ohun ìjà olóró ni ọwọ́ wọn tún bà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iléeṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà ní sísọ̀rọ ̀ òdì sí àwọn ọmọogun yóò domi tútù sí wọn lọ́kaàn ni, yóò sì ṣílẹ̀kùn sílẹ̀ gbayawu fún àwọn ọ̀tá láti ṣe ọ̀pọ̀ ọṣẹ́ fún ètò àbò orílẹ̀èdè Nàíjíríà.

Ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ yìí níí ṣe pẹ̀lú ìpè tí àwọn aṣòfin pè fún ìyọkúrònípò àwọn aṣíwájú ẹ̀ka iléeṣẹ́ ológun gbogbo lórílẹ̀èdè Nàìjíríà nítorí gbọnmọgbọnmọ ìkọlù àti ìpànìyàn tó ń wáyé.