Olùkọ́ OAU: Ẹ̀sùn àdínkù ọjọ́ orí àti ìbéèrè ìbálòpọ̀ lọ́nà àìtọ́ ni wọ́n fi kàn-án

Ọjọgbọn Akindele

Oríṣun àwòrán, ICPC

Àkọlé àwòrán,

Ohùn un ọ̀jọ̀gbọ́n Akindele tí o ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ ìgbà márùn ún lọ́wọ́ akẹ́kọ́bìnrin kan bọ́ sójú agbami ayélujára

Àjọ ti o n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, ICPC ti gbé olukọni fasiti ti wọn fẹsun kan pe o ṣe iduna-dura ibalopọ ati maaki pẹlu akẹẹkọbinrin kan ni fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile-Ifẹ, lọ siwaju ile ẹjọ giga kan nilu Oṣogbo,

Nibayii, adajọ ti wa pasẹ pe ki Ọjọgbọn Richard Akindele lọ jọkòó si ọgba ẹ̀wọ̀n báyìí.

Yátọ si ẹ̀sún pe o beere ibalopọ lọwọ akẹkọọ rẹ, wọn tun fi ẹsun kan pe o ṣe magomago ọjọ ori rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

World Toilet Day: Aráàlú ní woléwolé yẹ kó bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò ojúlé dé ojúlé

Ajọ ICPC ni, ọjọ ori to fi silẹ ninu ọrọ rẹ yatọ si eyi to wa ninu paali rẹ ti wọn ri ni fasiti OAU.

Wọn ni nigba ti wọn fọrọ wa lẹnu wọ, o ni ọdun 1961 ni wọn bi oun, eyi to yatọ si 1959 to wa ninu iwe fasiti rẹ.

Ọjọgbọn Akindele fi oju ba ile ẹjọ ni ọjọ Aje, ọjọ Kọkandinlogun oṣu Kọkanla, lori ẹsun mẹrin to da lori lilo ipo rẹ gẹgẹ bii olukọni ni ẹka imọ nipa akoso ati iṣiro, lati beere fun ibalopọ lọwọ akẹkọ kan ki o lee gba ọna eru fun un ni maaki ninu ọkan lara awọn ẹkọ rẹ.

Akindele to wa sile ẹjọ pẹlu agbẹjọro meji ni, oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.

Àkọlé fídíò,

'Oun tí Kunle Afolayan ṣe sí mi, mi ò lè ṣeé sí i'

Ọjọgbọn Richard Iyiola Akindele ni okiki rẹ kan loṣu kẹrin ọdun 2018 pe, o n beere ibalopọ igba marun un ọtọọtọ lọwọ akẹkọbinrin kan, Monica Osagie, ki o to lee yii esi idanwo rẹ kuro ninu awọn to fidirẹmi bọ si awọn to pegede.

Ajọ ICPC ni iwa ti o hu yii tako abala kẹjọ ofin iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria ti o si ni ijiya ti o tọ.

Ọjọgbọn Akindele ti beere fun eto ajọro bun mi-n-bun ọ ti oloyinbo n pe ni 'plea bargaining' lẹyin ti o ti gba pe oun jẹbi ẹsun naa.

Bakan naa lo tun tọka si ilera rẹ to ni ko ṣe deede gẹgẹ bii ara oun ti ko ni lee mu oun lagbara ati duro igbe aye ọgba ẹwọn.

O rọ ajọ naa lati boju wo ẹbẹ rẹ fun ajọro bun mi-n-bun ọ niwọn igba ti oun ti bẹrẹ ijiya lori ẹṣẹ naa lẹyin ti awọn alaṣẹ fasiti naa ti yọọ ni iṣẹ.

OAU lé ọ̀jọ̀gbọ́n tó bèèrè ìbálòpọ̀ fún máàkì

Oríṣun àwòrán, @OfficialOAU

Àkọlé àwòrán,

Ohùn un ọ̀jọ̀gbọ́n Akindele tí o ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ ìgbà lọ́wọ́ akẹ́kọ́bìnrin kan bọ́ sójú agbami ayélujára lọ́sẹ̀ tó kọja

Àwọn aláṣẹ fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, OAU nílu ilé ifẹ̀ ti pàṣẹ lọ rọọ́kún nílé fún ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akindele tí ẹ̀ka ìmọ̀ nípa ìṣirò owó tí wọ́n ní, o ń bèèrè fún ìbálòpọ̀ ìgbà máàrún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nítoríi máàkì.

Olùkọ́ náà n bèrè fún ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ́bìnrin tó fìdírẹmi nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ fún ìkẹ́kọ̀ọ́-gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kejì nínú ìṣàkóso okòòwò.Àṣẹ yìí wáyé lẹ́yìn tí ìgbìmọ̀ olùwádìí tí wọ́n gbe kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn aṣemáṣe tó rọ̀ mọ́ ìbáṣepọ̀ tí kò tọ̀nà, èyí tí wọ́n fi kan àgbà ọ̀jọ̀gbọ́n Richard Akíndélé ní fásitì ọ̀hún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn aláṣẹ fásitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, ní àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ náà ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé lóòótọ́ ni ọwọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé kò mọ́ lórí ẹ̀sùn yii.

Alukoro fásitì náà, ọ̀gbẹ́ni Abíọ́dún Ọláńrewájú ṣàlàyé nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú BBC Yorùbá pé àwọn méjèèjì yìí ní wọn pè síwájú ìgbìmọ̀ ọ̀hún ṣùgbọ́n arábìnrin tọ́rọ̀ kàn nínú fọ́nràn náà ko farahàn.

"Ìgbìmọ̀ yìí sàlàyé nínú àbájáde ìwádìí rẹ̀ pé ìwádìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé jẹ̀bi ẹ̀sùn aṣemáṣe tí kò tọ̀nà tí wọ́n fi kàn án.Lẹyìn tí gíwá fásitì yìí sì ti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò tó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jẹ̀bi, ó ti pàṣẹ kí ọ̀jọ̀gbọ́n Akíndélé ó lọ rọọ́kún nílé dìgbà tí wọ́n yóò parí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwádìí."Bákanáà ló ní Monica Usetobe Osagie ni orúkọ akẹ́kọ́́bìnrin tí ohùn rẹ̀ hàn nínú ìtàkùrọ̀sọ tó wáyé nínú ohùn tí wọ́n ká sílẹ̀ náà.