Àkókò tó láti gbẹ̀san lára ẹ̀fọ̀n mùjẹ̀mùjẹ̀

Àyẹ̀wò lórí ògùn ẹ̀fọ́n Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn eleyinju àánú ń gbèrò láti ṣe àgbékalẹ̀ dollar bilionu mẹta lé díẹ̀

Ọ̀nà àbáyọ tuntun láti gbẹ̀san lára ẹ̀fọn mujemuje tí yọjú.

Àwọn àṣẹwádìí ọmọ orílẹ̀èdè Kenya pẹ̀lú àwọn kan láti ilé ẹ̀kọ́ fún ìsègùn ní ìlú Liverpool lórí àìsàn ibà tí ṣàwárí oògùn tí ó jẹ́ májèlé fáwọn ẹ̀fon tí wọ́n bá ti fẹnu kan ẹ̀jẹ̀ ènìyàn.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Olugbenga Mokuolu to jẹ́ onimo nipa aisan iba ati ọ̀nà láti kojú rẹ̀ wípé májèlé ni ẹ̀jẹ̀ ènìyàn tó bá ti lo ògùn Ivermectin yóò jẹ́ fáwọn yàmùyámú.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà àbáyọ de láti gbẹ̀san lára Ẹ̀fọ̀n mùjẹ̀mùjẹ̀

Àbẹ̀wò ikọ̀ BBC sì láàbù àwọn àṣèwádìí ọ̀hún ní ìwọ̀-oòrùn Kenya fi hàn pé ẹnití o ba ti lo òògùn Ivermectin, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò jẹ májelè fáwọn ẹfon, èyí pẹ̀lú yóò jẹ́ ìrànwọ́ láti jẹ́ kí ẹ̀fọn má máa tàn kalẹ mọ́.

Ìrètí wà pé leyin ti ìwádìí bá kẹ́sẹ járí àìsàn ibà yoo di oun ìgbàgbé lágbaye. Èyí jẹ́ ọ̀nà làti mú ààrùn kúrò, nítorí náà, ó kú ẹ̀fọn nìkan tí kò sì lágbára mọ́ láti fi àìsàn sáwọn ènìyàn lára

Tẹ o bá gbàgbé ọmọ ọba Charles àti àwọn ẹlẹ́yinjú àánú yóò pàdé níbi àjọ Commonwealth láti ṣe àgbélakẹ̀ bílíọ̀nù mẹta lé ọwọ mejo dollar láti ṣe ìwádìí sì ọ̀nà àbáyọ lórí ààrùn ibà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: