Ìpínlẹ̀ Kaduna tún ti dá olùkọ́ 4,562 tuntun dúró

Nasir El-Rufai in blue attire Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Gómínà Nasir El-Rufai dá ogunlọ́gọ́ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ náà dúro l'ọdún tó kọjá

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kaduna tún ti dá àwọn olùkọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin àti ọ̀tàlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta lé méjì (4,562) dúró nínú àwọn ti wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà lẹ́hìn tí wọ́n ní kí olùkọ́ ẹgbẹ̀rún méjìlẹ́lógún (22,000) lọ rọ́kún nílé ní bíi oṣù márùń sẹ́hìn.

Àìpẹ́ yìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ náà fún wọn ní ìwé iṣẹ́, ṣùgbọ́n Kọmíṣọ́nà fún ètò Ẹ̀kọ́ ní Ìpínlẹ̀ Kaduna, Ja'afaru Sani, sọ wípé wọ́n pinu láti lé wọn lọ nítorí wípe ọ́gbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí ni wọ́n gbà wọlé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sani sọ wípé àjọ tí ó ńṣe àkóso ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ kọ́kọ́ gba àwọn olùkọ́ tí ó fẹ́ẹ̀ tó ẹgbàájọ sùgbọ́n nígbà tí wọ́n ṣe àwárí nípa ọ̀pọ̀lọ́pọ́ wọn, wọ́n ri wípé wọ́n rá pálá wọlé ni.

Ẹ ó rántí pé àríyànjiyàn bẹ́ sílẹ̀ ní ọdún tó kọjá nígbà tí Gómínà Nasir El-Rufai dá ogunlọ́gọ́ àwọn olùkọ́ ìpínlẹ̀ náà dúro látàri wípé wọn kò mọ iṣẹ́ to, tí wọ́n sì fìdí rẹmi nínú ìdánwò tí ó yẹ kí ọmọ ilé ẹ̀kọ́ apá kẹrin lè mọ̀.

Sani sọ fún àwọn oníròyin ní Kaduna lọ́jọ́rú ọ̀sẹ̀ pé ọ̀pọ̀lọ́pọ́ àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ lé dànù náà ni wọ́n kàwé gboyè gíga.