Nípínlẹ̀ Ògùn, Ọ̀gá ọlọpàá yìnbọn jẹ

Olopaa kan gbe ibon dani Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ìdílé olóògbé náà kò mọ ìdí tí olóògbé Agholor fi gbé ìgbésè náà

Ọ̀gá ọlọpàá kan tó ti fẹ̀yìntì tí orúkọ rẹ ń jẹ́ David Agholor, ti gb'ẹ̀mí ara rẹ̀ ní Ìjokò ní ìpínlẹ̀ Ògùn.

Agbenusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ náà, Abímbọ́lá Oyèyẹmí, sọ fún BBC wípé ọmọ olóògbé Agholor ló fi tó àwọn ọlọ́pàá létí wí pé bàbá òun ti yìn'bọn pa ara rẹ̀ lẹ́yìn tí ó jí tí ó sì wẹ̀ ni ọjọ́ Ọjọ́bọ ní ilé rẹ̀ tó wà lágbègbè Sheraton Estate tí ó wà ní Ìjokò.

Oyèyẹmí sọ wípé, "Olóògbé tí ó gbẹ̀mí ara rẹ̀ náà jẹ́ ọ̀gá fún àwọn ọlọpàá pàtàki tí ó ńkọjú ìjà sí àwọn ọlọ́ṣà ní ìpínlẹ̀ Enugu nígbà kan rí. Sùgbọ́n ó ti fẹ̀hìntì. Àwọn oluwádìí láti ilé iṣé ọlọ́pàá ti lọ sí ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti ṣẹlẹ̀ láti lo ya àworán ibẹ."

A gbọ́ wípé àwọn ará ilé olóògbẹ́ náà funra pé ìkan kò ṣe déédé pẹ̀lú rẹ̀ l'Ọjọ́rú, ṣùgbọ́n ó fi yé wọn wípé kò sí wàhálà rárá.

Ní ọjọ́ kejì, wọ́n sọ wípé bí ó ṣe jí, tí ó wẹ̀ tán ni kó gbogbo kọ́kọ́rọ́ ilé lé ọmọ rè obinrín lọ́wọ́. Àwọn ará ile rẹ̀ sọ wípé lọ bí ó ṣe lọ sí ẹ̀hìnkùle ni wọ́n gbọ́ ìró ìbọn.