Arsene Wenger njọ̀wọ́ ìdarí Arsenal

Wenger nju owo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Wenger ti lo ọdún mọ́kànlélógún gẹ́gẹ́bíi adarí Arsenal

Arsene Wenger tí ó jẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá ẹgbé agbábọ́ọ̀lú Arsenal yóò fi àlèéfà sílẹ̀ lẹ́hìn sáà yí.

Wenger tí ó ti lo ọdún mọ́kànlélógún gẹ́gẹ́bí adarí Arsenal nlọ 'lé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pẹ́ ó ṣì níi ọdún kan tí àdéhùn iṣé rẹ̀ yóò parí.

Olukọ̀ni fún ikọ̀ Arsenal náà tí ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínláàdọ́rin ni òun dúpẹ́ fún iye ọdún to ti lò gẹ́gẹ́bíi olùdari Arsenal.

Kíni àwọn olólùfẹ́Arsenal rí sọ síèyí?

Awọn ilumọ̀ọ́ká ti wọn ba BBC Yoruba sọrọ fi ohun dá meji lori ọrọ naa ni.

ninu ọ̀rọ̀ rẹ̀, Gbenga Adeyinka to jẹ gbajugbaja adẹrinpoṣonu lorilẹ̀ede Naijiria ni lilọ Arsene Wenger kọ̀ ni opin iṣoro ikọ Arsenal nitori, ni iwoye tirẹ, 'Wenger kọ ni i'soro Arsenal.'

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌrọ gbenga Adeyinka lori Wenger to fẹ fipo silẹ

Bakannaa, ilumọ̀ọ̀ka akọ̀rin takasufe ni, Sound Sultan ṣalaye pe ifẹyinti Arsenal yoo fun ẹgbẹ̀ agbabọ̀ọ̀lu Arsenal lanfani ati yẹ ọ̀na ayò miran wo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌrọ Sound Sultan lori Wenger to fẹ fipo silẹ

Bẹẹ gẹgẹ pẹlu lo fẹẹ̀ jẹ wi pe ero awọn ololufẹ ikọ naa kaakiri agbaye ko yatọ si ipa meji yii.

G'ẹ́gẹ́bí olùdarí Arsenal, Wenger mú oríṣiríṣi àrínyànjiyàn wá láàrín àwọn olólùfẹ́ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà. Púpọ̀ nínú wọn ni ó ti ń gbógun wípé kí ó máa lọ'lé.

Ogunlọ́gọ̀ àwọn tí ó ńwo eré bọ́ọ̀lù ní Nàìjíríà ni wọ́n ti ńfi èrò ọkàn wọn hàn l'órí ọ̀rọ̀ yí ní orí Twitter.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ si: