Koko iroyin: Ọdún ìlù l’Abẹ́òkúta, PDP fẹ́ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ míì

Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.

AfricanDrumFestival: Àwọn àwòrán tó làmìlaaka níbi ayẹyẹ.

Oríṣun àwòrán, AfricanDrumFestival

Àkọlé àwòrán,

"Kani a mọ pataki idagbasoke aṣa si idagbasoke eto ọrọ aje wa, a o tẹpa mọ"

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Muhammadu Buhari ṣe ileri atilẹyin fun idagbasoke aṣa

Ayẹyẹ àjọ̀dùn ìlù nílẹ̀ Áfíríkà to bẹ̀rẹ̀ nílú Abẹ́òkúta ni wọn ti maa n ṣe afihan ọkan o jọkan ilu iṣẹmbaye ati aṣa ilẹ Yoruba ati gbogbo Afirika.

Ninu ọrọ ti wọn sọ nibẹ, awọn eekan ọbalaye meji nilẹ Yoruba, Ọọni ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi Ọjaja II ati Alaafin ti ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi III gba awọn to wa nipo aṣẹ lẹka iṣejọba gbogbo niyanju lati rii wi pe wọn n ṣe koriya fun igbedide aṣa ilẹ Yoruba.

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ńgbèrò láti dà pọ̀ mọ́ àwọ́n ẹgbẹ́ míì

Oríṣun àwòrán, Kola Ologbondiyan/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ òsèlú PDP ńgbèrò láti dà pọ̀ mọ́ àwọ́n ẹgbẹ́ míì

Ẹgbẹ́ òsèlú Peoples Democratic Party ńgbèrò láti yí orúkọ́ wọn padà kó tó di ìgbà ìdìbò gbogbogbò ti ọdún 2019.

Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo ilé isẹ́ BBC pẹ̀lú akọ̀wé ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Ọ̀gbẹ́ni Kola Ologbondiyan jẹ́ kó di mímọ̀ pé ẹgbẹ́ òsèlú PDP kàn fẹ́ dàra pọ̀ mọ̀ àwọn ẹgbẹ́ míì fún ìdìbò ọdún 2019. E ka ekunrere re ni bii

Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni

Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC

Fidio wa fun toni

Ẹlẹ́wọ̀n kan gba máákì 248 nínú ìdánwò Jamb ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Ìkòyí ní ìlú Èkó.

Àkọlé fídíò,

Ẹlẹ́wọ̀n: Ẹ̀sùn ìbálòpọ̀ ọmọdé ló gbé dé mi dé ẹ̀wọ̀n