Àìsàn dá Ààrẹ àná ni Zimbabwe, Robert Mugabe, dùbúlẹ̀

Aworan Mugabe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ara Robert Mugabe ti di ara agba ti pẹ ṣugbọn o kọ lati fi ijọba silẹ

Igba kan ko lọ bi orere. Aarẹ ana lorileede Zimbabwe Robert Mugabe ko le rin mọ.

Aarẹ Emmerson Munagagwa to gba ijọba lọwọ rẹ lo tu keke ọrọ yi nibi iwode oselu kan lagbegbe Murombedzi.

Munagagwa ni o ti to oṣu meji ti Mugabe ti n gba itoju fun ailera ni orileede Singapore ti ko si le rin mọ latari aarẹ naa.

O ti pe ọdun kan ti wọn ni ki Mugabe fi ipo silẹ nitori ailera rẹ.

Munagagwa ko sọ pato iru aarẹ to n ba Mugabe finra sugbọn o ni Aarẹ ana naa ranṣẹ si oun pe ara ohun ti n balẹ ati wi pe ko ni pẹ ti ohun yoo fi pada wale.

Lọwọ ipari ijọba Mugabe, awọn eeyan bẹnu atẹ lu wi pe o ti n lo si ilu okere pupọ ju fun itọju ara rẹ.

Ọmọ ọdun mẹ́tàléláàdọ́rùn ún ni Robert Mugabe nigba ti o fi fi ipo silẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Mnangagwa ni o tu keke ọrọ aarẹ Mugabe silẹ

Lai pẹ yi ni Ilé ìgbìmọ̀ asòfin orílẹ̀èdè Zimbabwe pe ààrẹ̀ àná, Robert Mugabe láti wá fi àrídájú hàn nípa ohun tí ó sọ lórí jíjí òkúta iyebiye.

Ọ̀gbẹ́ni Mugabe nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan lórí ẹ̀rọ móhùnmáwòrán ti ìpínlẹ̀ kan fi ẹ̀sùn lílo àlùmọ̀kọ́rọ́yí fi jalè kan ilé isẹ́ tó ńrísí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèèrè.

Oríṣun àwòrán, JEKESAI NJIKIZANA/GETTY IMAGES

Ó ní "àwọn ilé isẹ́ náà ti kó wa lọ́rọ̀ lọ, àpò ìsúná kàn ti ri owó díẹ̀ ǹka bíi bílíọ̀nù mẹ̀ẹ́dógún dollar tí wọ́n ti ní

Kò tíì hàn yékéyéké bóyá Robert Mugabe ẹni ọdún mẹ́rinléláàdọ́rùún náà yóò fara hàn níwájú ilé asòfin Zimbabwe

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: