Àtíkù: Irọ́ ni pé mo fi $1,000,000 fẹ́‘yàwó tuntun

Àtíkù Abubakar pẹ̀lú obìnrin kan Image copyright @AtikuOrg
Àkọlé àwòrán Àtíkù ní òun kò fẹ́ ìyàwó tuntun

Igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ ní Nàíjíríà, tó tún jẹ́ olùdíje fún ipò ààrẹ, Àtíkù Abubakar, ti tako fídíò kan tí wọn ń pín kiri lórí ìtàkùn àgbáyé pe, òun fi mílíọ́nù kan dọ́là fẹ́ aya tuntun ní ìlú Dubai.

Àtíkù ní òfo, ọjọ́ kejì ọjà ni ìròyìn náà, tó sì jìnnnà sí òtítọ́.

Àtẹ̀jáde kan tí iléesẹ́ ìròyìn Àtíkù Abubakar fisíta lójú òpó Twitter rẹ̀ ní, àgbẹ́lẹ̀rọ lásán ni ìròyìn náà.

Image copyright @AtikuOrg
Àkọlé àwòrán Àtíkù wà níbi ìgbeyàwó Anthony Chuka-Douglas àti Whitney Erin Woods

O ní, Àtíkù Abubakar, àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́ àti Obi tìlú Onitsha, ni wọ́n dìjọ báwọn péjú sí ibi ayẹyẹ ìgbeyàwó Anthony Chuka-Douglas àti Whitney Erin Woods, níbití tí àwòrán náà ti jẹyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sùgbọ́n fídíò náà ló ti ń fa awuyewuye lórí àwọn òpó ìkànsíraẹni lórí ìtàkùn àgbáyé, tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà sì ń yọ sùtì ètè sí igbákejì ààrẹ tẹ́lẹ̀ náà.

Image copyright 'atikuorg
Àkọlé àwòrán Àtíkù Abubakar àti Obi tìlú Onitsha ni wọ́n dìjọ báwọn péjú sí ibi ayẹyẹ ìgbeyàwó náà