Àwọn ọmọ Nàíjíríà: Bí Wenger se ń lọ, ni Bùhárí yóò lọ

Muhammadu Buhari àti Arsene Wenger Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Buhari yóò kọ́gbọ́n lára Wenger

Ojú òpó ìkànsíraẹni Twitter ti kún nípa àwọn ọmọ Nàíjíríà tó ń fi bí Arsene Wenger se fẹ́ lọ wé bí Muhammadu Buhari yóò se lọ.

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó sọ̀rọ̀ lórí bí Arsene Wenger se ń gbèrò láti yẹ̀bá gẹ́gẹ́ bíi olùkọ́ni fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù Arsenal ní ìparí sáà ìdíje líígì yìí, ní ẹni ọdún méjìdínláàdọ́rin, ni ọ̀pọ̀ ọmọ Nàíjíríà ti gbé sí ẹ̀gbẹ́ ààrẹ Nàíjíríà, Muhammadu Buhari, tó ti pé ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin, tí wọ́n ló sì tún ń gbèrò láti gbé igbá ìbò ní ẹ̀ẹ̀kejì.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bolanle Victoria @bolaNLee_c ní bí Arsene Wenger se ń yẹ̀bá lẹ́ni ọdún méjìdínláàdọ́rin, tí Bùhárí tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rin sì fẹ́ gbé igbá ìbò ní lẹ̀ẹ̀kejì, a jẹ́ pé lóòtọ́ làwọn ọmọ Nàíjíríà ya ọ̀lẹ. O wá ń bèèrè pé "sé Aso Rock jẹ́ ilé ìfẹ̀yìntì ni?'

Dare Sunday @Letsmile ní, "ogún rere tí Wenger ń fi sílẹ̀ ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ tí Wenger nígbàgbọ̀ nínú wọn, tó sì mú ìdàgbàsókè báwọn, tó sọ wọ́n di ògo bọ́ọ́lù, bóyá Buhari yóò kọ́gbọ́n lára Wenger."

Fanklin Eze @frankdoma ń tiẹ̀ gbàdúrà pé Buhari yóò tẹ̀lé ipa ọ̀wọ̀, kó sì kọ̀wé fi isẹ́ sílẹ̀ bíi Wenger.

Linux @odolinus ní "tó bá jẹ́ pé Wenger setán láti kúrò lójú agbo lásìkò tí wọn ń yìn ín ni, Buhari náà leè kúrò tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, kó sì di àgba ìlú, dípò kó máa retí ó fìdí rẹmi bíi Wenger."

Díẹ̀ nínú èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà náà rèé