Òbí ọmọ Chibok kú nínú ìjàmbá ọkọ̀

àwọn ọmọ Chibok Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọdébìrin yìí ti wà ní àhámọ́ Boko Haram fún ọjọ́ pípẹ́.

Ọkan lára àwọn òbí awọn ọmọ ti ikọ̀ Boko Haram jí gbé ni Chibok ló ti jáláisí nínú ìjàmbá ọkọ̀ kan to wáyé lọ́jọ́ ìsinmi.

Ìjàmbá ọkọ̀ ọ̀ún ni a gbọ́ pé ó wáyé nígbà ti awọn obi náà fẹ́ lọ yọjú sí awọn ọmọ wọn tí wọ́n dá sílẹ̀ ní àhámọ́ Boko Haram tí wọ́n wà ní ile ẹ̀kọ́ gíga ti ilẹ̀ Amerika to wà ní Yola.

Ní ìlú Chibok ni awọn òbí awọn ọmọ òuń ti gbéra lati lọ sí ìlú Yola lọ yọjú sí àwọn ọmọ wọn.

Lágbede méjì ojú ọ̀nà ni ìròyìn sọ pe ọ̀kan lára àwọn awakọ̀ to wa ọkọ̀ oun lọ forísọ ọkọ̀ àjàgbé kan ti wọ́n fi ń sisẹ́ ojú ọ̀nà.