PDP: Kínni Bùhárí mú ti Commonwealth bọ̀?

Àmì PDP Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán PDP ní èyí kò sẹ̀yìn bí ààrẹ́ Nàíjíríà náà se ń sọ ọ́rọ́ òdì sáwọn ọmọ Nàíjíríà lára

Ẹgbẹ́ òsèlú alátakò ní Nàíjíríà, PDP, ti ń fi ìka hánu pé òfo, ọjọ́ kejì ọjà, ni bí ààrẹ Muhammadu Bùhárí se báwọn péjú sí ìpàdé àwọn olórí orílẹ̀èdè tó wà nínú àjọ Commonwealth, èyí tó wáyé ní ìlú ọba, United Kingdom.

Alukoro fún ẹgbẹ́ òsèlú PDP, Kọ́lá Ọlọ́gbọ́ndiyàn, nínú àtẹ̀jáde kan tó fisíta ní ìlú Àbújá ní, ẹnu kò ya àwọn rárá pé bí Bùhárí ti lọ, náà ló padà bọ̀, láì kó èrè kankan wálé.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKola Ologbodiyan: Jẹgudu jẹra ni ijọba APC

Ó ní, èyí kò sẹ̀yìn bí ààrẹ́ Nàíjíríà náà se ń sọ ọ́rọ́ òdì sáwọn ọmọ Nàíjíríà lára, tó sì tún pàtẹ irọ́ gẹ́gẹ́ bíi àwọn àseyọrí rẹ̀ fáwọn èèyàn tó gbàá ní àlejò.

Ààrẹ tiwa yege láti máse ìpolongo ànfààní ọrọ̀ ajé tó wà

Ọlọ́gbọ́ndiyàn ní, nígbà táwọn olórí orílẹ̀èdè míì nínú àjọ Commonwealth lo ànfààní àkókò náà láti se àfihàn ọ̀pọ̀ ànfààní tó wà ní orílẹ̀èdè wọn, ń se ni ààrẹ tiwa yege láti máse ìpolongo ànfààní ọrọ̀ ajé tó wà ní orílẹ̀èdè yìí, àmọ́ tó ń tàbùkù àwọn ọ̀mọ̀ orílẹ̀èdè yìí, pàápàá àwọn ọ̀dọ́