Onímọ̀ ọrọ̀ ajé: Ẹ mú ìyapa pàsípààrọ̀ Náírà kúrò

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Onímọ̀ nípa ẹ̀tò ọrọ̀ aje sọ pe yoo se ọrọ̀ ajé l'ánfààní ti kò bá sí ìyapa ninu síse pàsípààrọ̀ owó

Àjọ ayánilówó lágbàáyé, IMF, ti gba orilẹede Naijiria níyànjú lati fẹnu pàsípààrọ̀ owó dọ́la sí naira rẹ̀ jóná sí ojú kan soso.

Saájú àsìkò yii, orilẹede Naijiria ni ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀ tí wọ́n ń gbà se pààrọ̀ owó dọ́là, ninu èyí ti a ti rí pípààrọ̀ owó fún àwọn ti wọ́n n rìrìnàjò lọ sí Saudi Arabia, awọn tí wọn n sanwó ilé ẹ̀kọ́, ati awọn elépo rọ̀bì, tí ìlànà wọn kò báramu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọ Nàíjíríà: Àrímáleèlọ ni àríyá alẹ́ sátidé BB Naija

Olùdarí IMF, lẹ́ka Afrika, ọ̀gbẹ́ni Abebe Aemro Selassie sọ pe, òún faramọ́ bi banki àpapọ̀ Naijiria se n gbe ìgbésẹ̀ lati rii dájú pé kò sí ìyapa nínú síse pàsípààrọ̀ owó.

Nigba tí ó n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀, onímọ̀ kan nipa ètò owónàá ati ọrọ̀ ajé, Ọ̀gbẹ́ni Tunde Olatunji sọ fun BBC Yoruba pe, ìgbésẹ̀ tó dára ni bí ìjọba se fẹ́ ojúnà lati mú ìyapa kúrò nínú pàsípààrọ̀ owó dọ́la yii, ó ní ọ̀nà náà wà láti tuń mú kí ètò ọrọ̀ aje'ru'gọ́gọ́ síi.

Ẹ gbọ́ọ Ọ̀gbẹ́ni Tunde Olatunji siwaju si:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIMF gba Naijiria níyànjú lórí pàsípààrọ̀ owo Dola