Commonwealth: Ànfàní wo ni Nàìjíríà rí?

Aworan Ọbabìnrin Elizabeth keji Image copyright Twitter/Nigerian Presidency
Àkọlé àwòrán Orílẹ̀èdè mẹ́rìndínlógún ni Ọbabìnrin Elizabeth keji jẹ́ olórí fún nínú àjọ Commonwealth

Laipẹ yii ni ilẹ Gẹẹsi gba alejo awọn olori ajọ commonwealth ninu ipade kan to waye ni London.

Ọpọ ijiroro waye nibi ipade naa.

Sugbọn oun ti awọn ọmọ Naijiria n bere ni anfaani to mu wa.

Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo diẹ lara anfani to mu wa fun orileede Naijiria.

Image copyright Twitter /Nigerian Presidency
Àkọlé àwòrán Ireti wa pe idokowo naa yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje Naijiria

Ikunpa fun ọrọ aje laarin Naijiriaati il Gẹẹsi

Awọn onimọ nipa eto ọrọ aje ti tẹnumo pataki ṣiṣe ikunpa fun ọrọ aje laarin Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi.

Nibi ipade Commonwealth to pari laipẹ yii, anfani idokowo ogoje miliọnu poun jẹ yọ fun Naijiria ati orilẹede Pakistan.

Saaju àsìkò yii ni awọn ile iṣẹ ilẹ Gẹẹsi ti dokowo biliọnu marun poun sí Naijiria ti idokowo laarin Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi lọdọọdun si le ni biliọnu mẹta poun.

Image copyright Twitter/ FMPRng
Àkọlé àwòrán Ipade laarin Aarẹ Buhari ati Bernadus Van Buerden mu anfaani idokowo to to milionu mẹẹdogun dolla

Nibi ipade naa, ile iṣẹ Royal Dutch Shell ati aarẹ Buhari se ipade eleyii to bi ikede idokowo biliọnu mẹẹdogun dollar ni Naijiria.

Ipenija aarun iba

Ipade Commonwealth naa tun mu anfani ijiroro ati ijẹjẹ ọwọ iranwo lati koju aarun iba nilẹ Afrika.

Image copyright TWITTER/NIGERIAN PRESIDENCY
Àkọlé àwòrán Bill Gates ati orileede Naijiria ni asepo lati koju ààrùn rọmọlapa rọmọlẹsẹ ati aironje asaraloge jẹ fun awọn ọmọde.

Bill Gates to je eni to lowo ju lagbaye kesi awọn olori orilẹede Commonwealth lati fi kun iye owo ti won ya soto lati koju aarun iba.

Anfaani nla ni ẹjẹ owo biliọnu meji poun naa jẹ́ ti awọn olori orilẹede fun Naijiria, ọkan lara awọn orilẹede ti o n koju ipenija aarun iba.

Pẹ̀lu gbogbo anfani wọ̀nyii, o si ni awọn kan paapa julọ ninu ẹgbẹ alatako to ni awọn ko ri anfaani kankan ninu irinajo Buhari lọ si ipade naa.