N'ilu Èkó, ọkọ̀ agbépo gbiná

Ina njo lori titi l'Eko Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Èèyàn kankan kò fi ara pa

Ọkọ̀ agbépo kan ti gbiná ní Idiroko, ní òpópónà Ikorodu l'Ékòó, ṣugbọ́n bí iná náà ṣe bẹ̀rẹ̀ ni awakọ̀ ọkọ̀ náà fẹsẹ̀ fẹ.

Agbẹnusọ fun àjọ tí ó ńkojú ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìri ní ìpínlẹ̀ Ẹ̀kó, sọ fún BBC wípé wọn ko ti mọ ohun tí o fa iná náà lára ọkọ̀ tó gbé kerosínì náà.

Ó sọ wípé èèyàn kankan kò fi ara pa, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí kankan kò ṣ'òfò nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ọ̀sán ọjọ́ Ajé.

Iná náà fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ súnkẹrẹ-gbàkẹrẹ ọkọ̀ bí àwọn awakọ̀ kò ṣelè kọjá bí iná náà ṣe ńjó.

Kò pẹ́ lẹ́hin tí iná náà bẹ́rẹ̀ ni àwọn panápaná àti àjọ tí ó ńkojú ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìri d'omi pa iná náà.

Àwọn fọ́tò mìíràn láti ibi ìṣèlè náà rèé:

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Àwọn panápaná àti àjọ tí ó ńkojú ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìri ló d'omi pa iná náà

Ìròyìn tó ni létí wípé ọkọ̀ agbépo náà jó guruguru.

Image copyright LASEMA
Àkọlé àwòrán Ọkọ̀ agbépo náà jó guruguru

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọ Nàíjíríà: Àrímáleèlọ ni àríyá alẹ́ sátidé BB Naija

Related Topics