Ọwọ́ ba ọlọ́pàá mẹ́rin tó pa ọmọ Nàíjììrà ní S.Africa

Rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn àlejò àti àwọn ọmọ orílẹ̀èdè South Africa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìwà ìkórííra n pọ̀si ní orílẹ̀èdè South Africa

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ Muhammadu Buhari lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Abike Dabiri-Erewa sọ pé ọwọ́ òfin ti ba ọlọ́pàá mẹ́rin tó n fi ẹ̀mí àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàíjììrà ṣòfò ní orílẹ̀èdè South Africa.

Ọmọ ilẹ̀ Nàíjììrà kan tí ó fi orílẹ̀èdè náà ṣe ibùgbé, Clement Nwaogu ló ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ilẹ̀ náà jóo níná láàyè.

Alukoro ẹgbẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàíjììrà tí wọ́n ngbé orílẹ̀èdè South Africa Habib Miller sọ ọ́ di mímọ̀ pé ọmọkùnrin náà di olóògbé látàrí ìwà àífẹ́rí ẹ̀yà mìíràn tó gbòde kan nílẹ̀ náà.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìwà pípa àlejò gbòdekan ní orílẹ̀èdè South Africa

Ó sàlàyé pé ọmọkùnrin náà tí ó jẹ́ ọmọbíbí ìlú Njikoka ní ìpínlẹ̀ Anambra lùgbàdì ikú òjijì ní ìlú Rustenburg.

Miller fikún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé olóògbé náà jẹ́ onísòwó asọ àga ìjókò nígbà tí ó wà láyé.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìwà ìkórííra n pọ̀si ní orílẹ̀èdè South Africa

Àwọn tí ìsẹ̀lẹ̀ náà sojú wọn sọ pé Nwaogu rawọ́ ẹ̀bẹ̀ s'áwọn ọlọ́pàá sùgbọ́n wọ́n kọ etí ikún síi.

Àkọsílẹ̀ fihàn pé ọgọ́fà dín méjì ọmọ ilẹ̀ Nàíjììrà ló ti pàdánù ẹ̀mí wọn ní orílẹ̀èdè South Africa láti ọdún 2016 sí àkókó yìí.