Ọlọ́pàá àti Shiites tún fìjà pẹ́ẹ́ta

Awọn ọlọ́pàá ju tajutaju si aarin àwọn ọmọ ẹgbẹ Shi'ite Image copyright @OfficialPDPNig
Àkọlé àwòrán Wahala tún bẹ́ sílẹ̀ nílùú Àbúja láàrin àwọn ọlọ́pàá àti àwọn ọmọ ìjọ ẹ̀sìn shi'ite

Àwọn ọlọ́pàá tún kọlu àwọn ọmọ ìjọ ẹlẹ́sìn shi'ite níwájú olú ilé ẹgbẹ́ tó wà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn (National Human Rights Commission) nìlú Abuja, nígbàtí wọ́n ń fi ẹ̀hónú wọn hàn nítorí olórí wọn tó wà ní áhámọ́.

Ìròyìn sọ́ di mímọ̀ pé, àwọn márùndínláàdọ́fà ọmọ egbẹ́ náà ni àwọn ọlọ́pàá mú ní ọjọ́ kérìndínlógún osù kẹrin.

Ọ̀gá ọlọ́pàá kan tí kò dárúkọ ara rẹ̀ sọ pé, àwọn agbófinró fi ipá tú àwọn ọmọ egbẹ́ Shiites náà ká, nígbàtí wọ́n kọ̀ láti kúrò níwájú ilé National Human Rights Commission.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́ láti News Agency of Nigeria sọpé àwọn ọmọ egbẹ́ Shiites ju òkò lu àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n sì tún fọ́ gílàsìì àwọn ọkọ̀ tó wà níwájú ilé náà.

Sùgbọ́n agbẹnuso fún àwọn ọlọ́pàá nìlú Abuja Anjuguri Manzah kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí ìsẹ̀lẹ̀ náà. Ó wípé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò tíì té òhun lọ́wọ̀.