Ìsẹ̀lẹ̀ Ghana: Òògùn ẹ̀fọn pa ìbejì àti ẹ̀gbọ́n wọn

Ẹnìkan tó ń fín òògùn ẹ̀fọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awon òbí náà paapaa, fara kasa nínú ìṣẹlẹ ọhun

Awon aláṣẹ ni orílèèdè Ghana ti bẹrẹ iwadi nípa ìṣẹlẹ ikú ọmọ mẹta, lẹyìn tí wọn fa oogún oloro sínú.

A gbọ́ pe awon òbí wọn ní wọn fin òògún náà silẹ, lati fi pa kòkòrò ẹ̀fọn ninu ile wọn.

Awon ìbejì to jẹ obinrin, ti wọn jẹ ọmọ oṣù mẹ́sàn àti ẹgbọn wọn, to jẹ ọmọ ọdún méjì, pàdánù ẹmí wọn ní ilé ìwòsan ologun to wa ni ìlú Accra, ni kété ti wọn gbé wọn dé ibè.

Ìròyìn ta gbọ ni pe, Iya wọn fin ogún oloro náà silẹ̀, lati dẹkùn bi ááyán ṣe n daamu wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọ Nàíjíríà: Àrímáleèlọ ni àríyá alẹ́ sátidé BB Naija

Awon òbí náà paapaa, fara kasa nínú ìṣẹlẹ ọhun eyi to se akoba fun mimi soke silẹ wọn, bi o tilẹ́ jẹ pe ara wọn pada ya.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Èyí kìí sì se ìgbà àkọ́kọ́ tí irúfẹ́ ìsẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò wáyé

Se ni àwòrán oogún oloro náà gba ori ẹrọ ayelujara kan lẹyìn ìṣẹlẹ náà.

Ọmọbìnrin ìbejì, ọmọ ọdún mẹẹdogun naa ku ni Kumasi

Eyi kii si se igba akọkọ ti irufẹ ìṣẹlẹ bẹẹ yóò wáyé ni orílèèdè Ghana.

Lọdun 2016, àwọn ọmọbìnrin ìbejì, ọmọ ọdún mẹẹdogun ku ni ilu Kumasi, lẹyìn tí wọn sun inu yàrá ti won fin ogún oloro apakokoro si.

Related Topics