Ìkọlù Benue: Adaran pa àlùfáà méjì, ọmọ ìjọ 13 nílé ìjọsìn

Àwọn èrò gbé pósí àwọn ti darandaran pa ní Benue Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Bíi ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ ènìyàn ni ó ti kú ní Benue láti 2013

Ìròyìn kàn ní àwọn afurasí darandaran agbébọn ti pa àlùfáà méjì àti ọmọ ìjọ mẹ́tàlá ní ilé ìjọsìn kátólíìkì kan tí ó wà ní Ayar Mbalom ní ìjọba ìbílẹ̀ ìlà oòrùn Gwer ní ìpínlẹ̀ Benue.

Àwọn afurasí darandaran náà ni a gbọ́ pé ó ṣe ikọlù náà sí St. Ignatius Quasi Parish, Ukpor-Mbalom ní bíi aago mẹ́fà àárọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun nígbà tí àwọn olùjọ́sìn ìjọ náà lọ sí ìjọ́sìn àárọ̀.

Terver Akase ti ó jẹ́ agbẹnusọ fún Gomina Samuel Ortom sọ fún BBC Yorùbá pé, awon fadá ti o padanu ẹ̀mi wọn ninu ikolu naa ni Fadá Joseph Gor ati Fadá Felix Tyolaha.

Akase so wí pé lẹ́hìn tí àwọn darandaran náà ṣọṣẹ́ tán ní ilé ìjọsìn náà, wọ́n tún sọ iná sí ilé bíi àádọ́ta ní ìlú náà, kí wọn tó sa lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOdumakin sọrọ lori Fulani darandaran

Ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ ènìyàn ni ó ti kú ní Benue láti 2013

Oṣù kejì ọdún yìí ni kọmíṣọ́nnà fún ìbánisọ̀rọ̀ àti ìlanilọ́yẹ ní Benue, Lawrence Onoja, sọ wí pé bíì ẹgbẹ̀rún kan àbọ̀ ènìyàn ni ó ti kú ní Benue láti 2013 nínú àkọlù àwọn afurasí darandaran agbébọn, tí ogunlọ́gọ̀ sì pàdánù dúkìá, ohun ọ̀gbìn àti ilé wọn.

E ó rántí wípé ní oṣù kínní ọdún yìí ni ìjọba ìpínlẹ̀ Benue sin òkú métàléláàdọrin tí àwọn agbébọn pa.