Ọṣínbàjò: Èmi kìí gbé ilé rárá nítorí iṣẹ́ ìlú

Yẹmi Ọṣinbajo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ipò adarí kò rọrùn rárá

''Iṣẹ́ ń bẹ níwájú igbákejì ààrẹ''

ÈyÍ ni ọ̀rọ̀ to jade lẹnu Ọjọ̀gbọ́n Yẹmí Ọṣínbàjò lásìkò ti o n ka ìwé setigbọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé iwé LEA nilu Àbújá lati fisàmì àyájọ́ ọjọ́ ìwé àti òfin àdáni lágbàyé fún t'ọdún 2018.

Ọrọ yìí jẹyọ ninu atẹjade kan lati ọwọ oluranlọwọ fun igbákejì ààrẹ lori ọrọ iroyin, Laolu Akande.

Ọjọ̀gbọ́n Yẹmí Ọṣínbàjò ni iṣẹ́ adarí yala nípò ààrẹ tàbí nípò igbákejì rẹ̀ ''kìí ṣe kékeré rárá fún ẹni tó bá fẹ́ sin ìlú nítòótọ́.''

Ó ni lọ́pọ̀ igba ni òun máa ń rin ìrìnàjò káàkiri lati le se irawon fun ààrẹ lẹ́nu iṣẹ́ ìlú t'àwọn jìjọ gba.

Ìmọ̀ràn f'áwọn Adarí

Yẹmí Ọṣínbàjò gba àwọn olórí nímọ̀ràn pé, kí wọ́n tẹ̀lé òdiwọ̀n gbèǹdéke iye ọdún tí òfin bá là kalẹ̀ fún wọn, yálà ọdún mẹ́rin ni tàbí ọdún mẹ́jọ.

''Ó yẹ kí olórí lè sinmi, kí ó tún rí ààyè fún ẹbí àtí ará rẹ̀.''

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAgbẹnusọ Mélayé: Dino ti lọ yọjú sọ́dọ̀ ọlọ́paa SARS