2019 Election: Olasunkanmi Okeowo ní òun kò díje fun ipo ààrẹ mọ

Olasunkanmi Okeowo

Oríṣun àwòrán, Okeowo/instagram

Àkọlé àwòrán,

Orí àtẹ̀jíṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀ ló ti kéde pé òun yọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ òun lẹ́yìn tó sọ pé àwọn aláwọ dúdú ò lè ronú láti ṣẹ̀dá ohunkohun.

Olasunkanmi Okeowo, tó fẹ́ díje fún ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́dún 2019, lábẹ́ àsía African Democratic Congress (ADC) tí sọ pé, òun kò díje fún ipò ààrẹ mọ lẹ́yìn tó sọ̀rọ̀ kan eyi tó bí àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú.

Orí àtẹ̀jíṣẹ́ ẹ̀rọ ayélujára rẹ̀ ló ti kéde pé, òun yọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ òun lẹ́yìn tó sọ pé, àwọn aláwọ dúdú kò lèe ronú láti ṣẹ̀dá ohunkohun.

Nínú ìfọrọ̀wánilẹ̀núwò kan tí Folarin Falana (Falz) àti Laila Johnson Salami ṣe fún-un, lóri òhun ti yóò ṣe láti mú ǹkan dáradara se tó bna dé ipò ààrẹ.

Awọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ayefẹlẹ: Orí ìkúnlẹ̀ ni ìyàwó mi wà, tó ń bẹ gómìnà, láti 11pm si 4am

Nínú èsì rẹ̀, Olasunkanmi ní aláwọ dúdú ni wa, à kó lee da ǹkankan se bí àwọn oyinbo tí máà ń ṣe, bi wọn tilẹ̀ tí wa mọ inu yàrá kan fun odidi ọdun kan.

Lẹ́yìn ti fọran náà dé ìgboro lóri àyélujára ní àkàrà bá tú sepo fún olùdíjè náà, èyí ló mu ṣe ìpinnu pé oun kò díje dupo ààrẹ mọ.

Lẹ́yìn náà ni ọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní jà rain-raín lórju opo twitter.

Kínní ero àwọn Nàìjíríà lori ọrọ yii loju opo Twitter:

Ó dàbí ẹni pé gbogbo èèbú yìí ló fà idí abajọ ti Ọkẹowo fí sọ pé òun ò ṣe mọ ooo

Atiku Abubakar ní sáà kan ní òun tọrọ lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Atiku Abubakar ní kò sí tipá nínú kí òun di àarẹ́ Nàíjirìa

Igbákejì ààrẹ àná lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Atiku Abubakar tí rọ awọn ọmọ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà láti gbà òun láàyè, lati lo sáà kan soso gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Abubakar sọrọ ọhún níbi ìfọrọwanilẹnuwo kan táwọn akọ̀ròyìn se fun. O ní láì jẹ́ pé enikẹni bèèrè lọ́wọ́ òun, ohun to bójúmu láti ṣe ni, tori ohun ti ìgbàgbọ òun rọ mọ láti ṣe ni.

"Bí mo ba di ààrẹ ní ọdun 2019, mo ti fi ohùn sílẹ̀ láti ṣe sáà kan ṣoṣo'

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ìyá Darasimi: Ọlọ́run fi ìbejì rẹ̀ mí lẹ́kún, lẹ́yìn ikú Darasimi tó mu sódà

Ó ní bótilẹ̀ jẹ́ pé Buhari náà jẹ́ irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọdun 2011 tí kò sì tèlée, ọ̀rọ̀ tohun kò ni rí bẹ́ẹ̀ rárá àti pé, òhun ti ṣetán láti tọwọbọ ìwé àdéhun.

Atiku fii kún-un pé, àwọn ọmọ Nàìjíríà le gbé ìwé jáde fún òun lati tọwọ́ bọ̀ọ́ fún ẹ̀ri ọjọ́ iwájú, bí òún bá fẹ́ yẹ̀ kúro lórí àdéhùn.

Atiku: Kò pọn dandan kí ń díje fún ipò àarẹ́ Nàíjirìa

Igbákejì àarẹ́ Nàíjirìa tẹ́lẹ̀rí Atiku Abubakar, ti ní, òun kò sọpé ó pọn dandan fún òun láti jẹ àaré orílẹ́èdè Nàíjirìa ní ọdún 2019.

Atiku sọ pé tí ó bá jẹ́ pé ó pọn dandan ni, òun kò bá má gbà rárá fún M.K.O. Abíọ́lá láti dìje fún ipò àarẹ́ nínú ìdìbò ọdún 1993.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atiku: Itàn mi nínú òṣèlù

Ó mẹ́núba ìrírí rẹ̀ sẹ́yìn pé tí áwọn ọmọ orílẹ́-èdè Nàíjirìa bá wo ìtàn òun nínú ètò òṣèlù Nàíjirìa, wọn yóò ri pé òun kìí se olóṣèlù bó-báa-o-pá; bó-bàa-o-bùú-lẹ́sẹ̀.

Atiku sọ pé òun wọlé gẹ̀gẹ̀ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa ní ọdún 1999, kí òun tó di igbákejì àarẹ́ Olúsẹ́gun Obásanjọ́ l'ọdún kan náà.

Ó sọ pé òun díje fún ipò àarẹ́ pẹ̀lú olóyè Olúsẹ́gun Obásanjọ́ ní ọdún 2007 láti fihàn wí pé òun lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni gẹ́gẹ́ bíi ọmọ Nàíjirìa.