Siasia lè gba iṣẹ́ akọ́nimọ̀ọ́gbá égbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Cameroon

Akọ́nimọ̀ọ́gbá Super Eagles tẹ́lẹ̀ rí: Samson Siasia Image copyright Twitter/Siasia
Àkọlé àwòrán Samson Siasia wà lára àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá tí àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní orílẹ́èdè Cameroon fẹ́ fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò

Akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles tẹ́lẹ̀ rí, Samson Siasia, wà lára àwọn akọ́nimọ̀ọ́gbá mẹ́tàdínlọ́gọ́rin tí àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní orílẹ́èdè Cameroon fẹ́ fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò láti tukọ̀ ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ náà.

Àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù àfẹsẹ̀gbá ní Cameroon ń wá ẹni tí yóò rọ́pò Hugo Broos látàrí bí orílẹ́-èdè náà ti kùnà láti yege nínú àwọn tí yóò kópa nínú ife ẹ̀yẹ àgbáyé ọdún yìí ní orílẹ́-èdè Russia.

Àwọn míràn tí wọ́n tún yàn fún àyẹ̀wò fún isẹ̀ náà ni: Balógun ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Cameroon tẹ́lẹ̀rí, Rigobert Song; akọ́nimọ̀ọ́gbá ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Super Eagles nígbàkan rí, Philippe Troussier; àti akọ́nimọ̀ọ́gbá égbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ilẹ̀ Faransé tẹ́lẹ̀ rí, Raymond Domenech.

Olórí ìgbìmọ̀ tó ń rí sí yíyan akọ́nimọ̀ọ́gbá míràn fún orílẹ́-èdè Cameroon, Djomo Kelvin, sọ pé àwọn yóò se àyẹ̀wò fínífíní kí awọ́n tó yan akọ́nimọ̀ọ́gbá tuntun fun égbẹ́ agbábọ́ọ̀lù ọ̀hún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ó dèèwọ̀ láti sọ ilégbèé di iléèjọsìn l'Ékó

Èèyàn mẹ́wàá kú nínú ìkọ̀lù tuntun ni Benue