Sàyẹ̀wò agolo òògùn apakòkòrò rẹ  kí o tó lòó
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Ọmọ Nàìjíríà: Òògùn apakòkòrò fẹ́ẹ̀ sọ mí d'èrò ọ̀run

Nínú ìfọ̀rọ̀wánílẹ́nu wò BBC Yorùbá, ni àwọn ènìyàn ti sàlàyé àwọn ìsòrò tí wọn ti kojú, nínú lìlò òògùn apakòkòrò, pàápàá òògùn ẹ̀fọn.

Abilékọ Bukola Olúbayode sàlàyé pé, díẹ̀ lókùn kí oun d'ẹni àgbégbìn lásìkò kan tí wọn fín inu ile pẹ̀lú òògùn apakòkòrò láì gbàá láàyè kí ó ṣiṣẹ́ tán, kí wọ́n tó sùn.

Ní ti Abilékọ Oyèyẹmí Ọlọ́runfẹ́mi, ó sàlàyé pé Òun kìí lòó nítorí àwọn ìjàmbá tí ó sodo nínú rẹ̀, Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ó ṣeeṣe kí ènìyàn fi ọwọ́ rẹ̀ sẹ́nu láìmọ̀ tí ó sì lè dí májèlé