NAFDAC: Fifi òògùn apakòkòrò 'Sniper' sinu ẹwà leè jásí ewu

aworan ẹwa
Àkọlé àwòrán,

Ẹwa jẹ ounjẹ aayo fun ọpọlopọ ni Naijiria

Bi iwọ tabi mọlẹbi rẹ ba fẹran ẹwa ni jijẹ, tete yaa tẹti si ikede pataki yi.

Onimọ nipa ounjẹ jijẹ, Oluwatobi Oyedeji ninu ọ̀rọ̀ to ba BBC News Yoruba sọ, sọ pe ounjẹ ti a ko ti i ṣe to ba ni kokoro ninu tumọ si pe ounjẹ ti wọn ko fi kẹmika kankan gbin ni.

O ṣalaye pe lilo kẹmika bi oogun ẹfọn tabi 'sniper' maa n ba ẹya ara jẹ́ diẹdiẹ ni tabi ko pa eniyan l'oju ẹsẹ. Ẹ gbọ ọ ni ẹkunrẹrẹ.

Àkọlé fídíò,

Lílo òógùn apakòkòrò fún oúnjẹ l'éwu

Ṣaaju ni ajọ to n mojuto ipese ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, kilọ fun awọn ọmọ Naijiria lati yago fun awọn ounjẹ ti wọn ba fi kẹmika 'sniper' ṣe lọ́jọ̀.

Kẹmika naa, Dichlorvos dimethyl phosphate, ti gbogbo eniyan mọ si 'sniper' jẹ gbaju-gbaja kẹmika ti ajọ NAFDAC fọwọ si lati maa fi pa kokoro bi ẹfọn.

Laipẹ yii ni iroyin kan jade sita pe awọn kan n lo kẹmika naa lati fi ṣe ounjẹ wọn lọjọ, ko ma ba a bajẹ, ṣugbọn ajọ NAFDAC ti sọ pe o lewu fun ilera ara.

Daniel Ekugo, to jẹ ọga agba fun ileeṣẹ to n daabo bo ẹtọ awọn onraja, fi idi rẹ mulẹ pe lootọ ni awọn oniṣowo kan n lo 'sniper' lati fi tọju ẹwa ti wọn n ta, ati lati fi pa awọn kokoro ro n sapamọ sinu ẹwa.

Ekuko ni oun ko gbagbọ pe awọn ksn le ma a hu iwa buruku bẹ.

Eyi lo wa mu ki ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Christiana Mojisọla Adeyẹye, gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran pe ki wọn ma ṣe ra tabi jẹ ounjẹ ti wọn fi 'sniper' tabi kẹmika oloro mi i pa.

Ati pe, o ṣe pataki lati fọ ounjẹ wọn daada ki wọn o to se e nitori pe jijẹ ounjẹ ti 'sniper' wa lara rẹ le fa oju fifọ, gìrì, eebi, ìgbẹ́ gbuuru, to fi mọ jẹjẹrẹ tabi ko tilẹ pa ẹni naa.

O gba awọn eeyan niyanju lati ri wi pe wọn fi omi ṣan ẹwa wọn daada ki wọn to daa si ori ina

Irufẹ iṣẹlẹ aṣilo oogun apakokoro o jẹ tuntun

Ọmọ mẹ́ta láti inú ìyá kan náà kan gbẹ́mì mì nítorí òògùn apakòkòrò tí wọn fà símú.

A gbọ́ pe awon òbí wọn ní wọn fin òògún náà silẹ, lati fi pa kòkòrò ẹ̀fọn ninu ile wọn.

Awon ìbejì to jẹ obinrin, ti wọn jẹ ọmọ oṣù mẹ́sàn àti ẹgbọn wọn, to jẹ ọmọ ọdún méjì, pàdánù ẹmí wọn ní ilé ìwòsan ologun to wa ni ìlú Accra, ní orílẹ-èdè Ghana ni kété ti wọn gbé wọn dé ibè.

Ìròyìn ta gbọ ni pe, Iya wọn fin ogún oloro náà silẹ̀, lati dẹkùn bi ááyán ṣe n daamu wọn.

Ewu tó rọ̀ mọ́ lilo oogun apakokoro

Níwọ̀n ìgbà tí kò sí ibi tí ìṣe kò sí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń lo òògùn apakòkòrò ní órílẹ̀-èdè Nàìjíríà bákán náà, èyí ló mú kí BBC Yorùbá ṣe ìwádìí àwọn ewu tí àwọn ènìyàn ti bá pàdé nínú lílo òògùn apakòkòrò.

Ẹ gbọ́ ohun tí wọn sọ.

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Àwọn ènìyàn sọ àwọn ewu tí wọn pàdé nínú lílo òògùn ẹ̀fọn

Dókítà Yemisi Adeyeye ní ọ̀pọ̀ ènìyàn ló màa lo òògùn apakòkòrò fún ẹ̀fọn, aáyán àti ìdun, sùgbọn kàkà kó jẹ́ ohun ààbò, ìpalára ni ó jẹ́ fún elòmíràn.

Ó wá gba àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ràn pé, ó ṣe pàtàkì láti yẹ agolo òògùn apakòkòrò wò, kí a sì tèlé ìlànà tó yẹ kí a tó lòó

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Dókítà Yemisi Adeyeye sàlàyá lórí àwọn ìpalára tó wà nínú òògùn apakòkòrò