Nwaboshi: Sẹ́nétọ̀ ń lọ ilé ẹjọ́ ní Ọjọ́rú -EFCC

Nwaboshi ń rẹ́rìn ín

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán,

EFCC rá sẹ́nétọ̀ náà mú ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá yìí lórí ẹ̀sùn pé ó ṣe jìbìti biliọnu mẹfa náírà

Agbẹnusọ fún àjọ tí ó ń kojú ìwà jẹgúdújẹrá (EFCC), Wilson Uwujaren, ti sọ wí pé sẹ́nétọ̀ láti ìpínlẹ̀ Delta,

Peter Nwaboshi, yóò fojú ba ilé ẹjọ́ ní Ọjọ́bọ, lórí ẹ̀sùn pé ó ṣe jìbìtì bílíọ́nù mẹ́fà naira (N6bn).

Uwujaren sọ fún BBC Yorùbá nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí àjọ náà ṣe gbé Nwaboshi tì mọ́lé kọjá ọjọ́ méji (wákàtí méjìdínláàdọ́ta) tí òfin fà lélè, pé, èyi'wáyé nítorí wí pé àjọ náà ń ṣètò ìwé ẹ̀sun rẹ ni.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Agbẹnusọ Mélayé: Dino ti lọ yọjú sọ́dọ̀ ọlọ́paa SARS

EFCC rá sẹ́nétọ̀ náà mú ní òpin ọ̀sẹ̀ tó kọjá, lórí ẹ̀sùn pé, ó ṣe jìbìti biliọnu mefa, àti pé ó fi ilé-iṣẹ́ márùndínlógún gba iṣẹ́ àgbàṣe gẹ́gẹ́ bí olórí ìgbìmọ̀ asòfin àgbà lórí ọ̀rọ̀ Niger-Delta.

Àjọ náà ní pé ó tó ọdún méjì sẹ́hìn tí àwọn kan ti kọ ìwé mọ́ọ tí àwọn sì ti ń dọdẹ Nwaboshi.

Nwaboshi ni ó ń ṣojú ẹkùn àríwá Delta ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà nílu Àbújá.