Fani-Kayode: Iwà Dino dójútini gẹ́gẹ́ bí olóṣèlú

Image copyright Twitter
Àkọlé àwòrán Fídíò ṣe àfihàn Dino níbi tí o joko sí ilẹ̀ l'ojú títì ní Ábuja

Mínísítà nígbà kan rí, Femi Fani-Kayode, ti bẹnu àtẹ́ lu ìwà Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ń gbée látì Abuja lọ sí Kogi tí ó sì fẹsẹ̀ fẹ.

Ẹ ó rantí wí pé ní ọjọ́ ìṣẹgun ni ìròyìn gbálẹ̀ pé Dino ti jọ̀wọ́ ará rẹ̀ fún àwọn ọlọ́paa. Kò pé sí ìgbà náà ni àwọn fídíò bẹrẹ sí ní gba orí ẹ̀rọ ayélujára, to ṣe àfihàn Dino níbi tí o joko sí ilẹ̀ láàrin ojú títì ní Ábuja.

Fani-Kayode sọ lórí Twitter ní Ojoru wí pé bí Melaye ṣe hùwà nínú fídíò ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò fi akin àti iyì hàn.

Ó ní, kò yẹ ènìyàn tó jẹ́ Sẹ́nétọ̀ hùwà bẹ́ẹ̀, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé òun kórira bí Aare Muhammadu Buhari ṣe ń ṣe sí àwọn tí ó gbe sórí oyè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics