Àwọn aṣòfin so ìjókòó rọ̀ nítorí Dino Melaye

Asofin Dino Melaye Image copyright @dinomelaye
Àkọlé àwòrán Asofin Melaye ti figba kan korin 'Ajekun Iya' si awọn alatako rẹ ni ọdun 2017.

Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l'Abuja ti fún ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní orílẹ̀-èdè Nàíjìrà Ọgbẹ́ni Ibrahim Idris ní gbèǹdéke ọjọ́ kan láti wá farahàn níwájú ilé.

Wọ́n ní kó wá sàlàyé fún ilé bí àwọn agbófinró tí sètò bí wọ́n ti se mú Sẹ́nẹ́tọ̀ Dino Melaye l'ọ́jọ́ Isẹ́gun.

Kódà wọ́n so ìjókòó fún ọjọ́rùú rọ̀ kí gbogbo ilé lè l'àǹfání láti lọ ṣe àbẹ̀wò sí Dino ní ilé ìwòsaǹ.

Adeoola Soetan bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àwọn olóṣèlú lórí iṣẹ́ ọwọ́ wọn pé bí àwọn agbófinró ṣe mú Sẹ́nẹ́tọ̀ Dino Melaye yẹn dára.

Kí ó lè jẹ́ àwòkọ́ṣe fún àwọn tó kù

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn aṣòfin so ìjókòó rọ̀ nítorí Dino Melaye

Èwẹ̀, alákóso ẹgbẹ́ tó n rí sí bí ìjọba àwarawa yóo ṣe fẹsẹ̀ múlẹ̀, ọ̀gbẹ́ni Adéọlá Ṣóẹ̀tán, sọ pé, Dino ń se àpèjúwe bí àwọn olóṣèlú orílẹ̀-èdè Nàíjìrà ti rí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: