Àwọn olólùfẹ́ Bayern Munich ya wọ orí pápá lẹ́yìn ìdíje

Ikò agbábọ́ọ̀lù alátakò Real Madrid lu Bayern Munich mọ́lé Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Àwọn olólùfẹ́ Bayern Munich yarí fún ọmọ egbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà

Àjọ tó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù nílẹ̀ aláwọ̀ funfun-UEFA ti fi ẹ̀sùn kan ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Bayern Munich lẹ́yìn tí àwọn olólùfẹ́ wọn ya wọ orí pápá.

Eléyìí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí Bayern Munich fìdí rẹmi pẹ̀lú ayò kan sí méjì nínú ìfẹsẹwọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú ikọ̀ Real Madrid nínú eré bọ́ọ̀lù tó kángun sí àṣekágbá Champions League.

UEFA tún fẹ̀sùn kàn ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù náà pé àwọn olólùfẹ́ wọn ṣ'àfihàn àtẹ tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ àlùfàńṣá sí nínú pápá ìṣeré wọn.

Ọkan lára àwọn olólùfẹ́ wọn tilẹ̀ faṣọ mọ́ agbábọ́ọ̀lù wọn, Frank Ribery, lọ́rùn nígbà tí òmíràn ya fọ́tò pẹ̀lú ọmọ agbábọ́ọ̀lù alátakò Real Madrid lẹ́yìn tí ìfẹsẹwọnsẹ̀ náà parí

Ìgbẹ́jọ́ náà yóò wáyé ní ọjọ́kọkànlélọ́gbọ̀n osù karùn ọdún yìí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Related Topics