ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ èèyàn bẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìbẹ̀wò Dino láìṣe iṣẹ́ ìlú

Awran Dino Melaye Image copyright Aminu Omoye
Àkọlé àwòrán Ọnà tí Dino fi farapa ninu ìṣẹlẹ náà ko ti daju

Òrọ̀ ti bẹ́yìn yọ báyìí

látàrí bí àwọn ọmọ Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l'Abuja ti so ìjókòó rọ̀ nítorí Dino Melaye lọ́jọ́rùú láti lọ ṣàbẹ́wò sí Dino Melaye

Àwọn Sẹ́nẹ́tọ̀ náà korò ojú sí bí àwọn ọlọ́ọ̀pá ṣe mú Dino Melaye tí gbogbo wọn sì lọ wòó ní ilé ìwósàn.

Sùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà.

Àwọn kàn sọ pé, àwọn aṣòfin àgbà kó ọ̀rọ̀ náà kù, nítorí wọn kò lọ sí ìpínlẹ̀ Benue nígbà tí àwọn darandaran f'ẹ̀mí àwọn aláìṣẹ̀ ṣòfò.

Bẹ́ẹ̀ni wọn kò lọ sí Maiduguri níbi tí Boko Haram tí n fi ẹ̀mí àwọn ènìyàn ṣòfò.

Àbádòfin ogún ni àwọn Sẹ́nẹ́tọ̀ kò bá jíròró lé lórí nígbàtí ti wọ́n so ìjókòó ilé rọ̀ nítorí Dino Melaye lọ́jọ́ rùú.

Àwọn kàn ti ẹ̀ ńretí ìgbàtí àwọn aṣòfin àgbà l'Abuja yóò se àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Benue àti Maiduguri lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti lọ wo Dino Melaye ní ilé ìwósàn.

Image copyright @dino_melaye
Àkọlé àwòrán Iléesẹ́ ọlọ́pàá ní, àwọn ti fi orúkọ Mélayé tó iléesẹ́ ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àgbáyé, Interpol, létí

Ó jẹ́ íyàlẹ́nu pé, nínú gbogbo àwọn Sẹ́nẹ́tọ̀ tó lọ wo Dino Melaye ní ilé ìwósàn, àwọn méjì péré ni àwọn ọlọ́pàá fààyè gbà láti ríi.

Eni tó lójú lojú tì. Èrò àwọn míràn ni pé àwọn ọmọ Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà l'Abuja kò lojútì. Ìgbésẹ́ yìí sì lè s'àkóbá fún àwọn ọmọ wọn lẹ́yìnwá ọ̀la.

ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló fàáké kọ́rí wípé kí àwọn Sẹ́nẹ́tọ̀ se àbẹ̀wò sí ìpínlẹ̀ Benue

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀìsàn ibà; Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa lílo ewé áti egbò