Mnangagwa: Ija Zimbabwe pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dópin lẹ́yìn ogún ọdún

Aare orile ede Zimbabwe: Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ààrẹ Mnangagwa ilẹ̀ Zimbabwe: ara kìí sá fún ara

Aarẹ orílẹ̀ èdè Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa, ní ìjà dópin, ogun sì tán

Ó ní àjọṣepọ̀ orílẹ̀ èdè náà pẹ̀lú ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ padà lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tí ààrẹ àná, Robert Mugabe, kò ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè méjéèjì kò wọ̀ tẹ́lẹ̀.

Ọ̀rọ̀ orílẹ̀ èdè méjéèjì foriṣọ́npọ́n ní ọdún 1997, nígbà tí olórí ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì nígbà kan rí, Tony Blair, yọwọ́ kùrò nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí ọ̀rọ̀ àtúntò ilẹ̀ tí Robert Mugabe gbé kalẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nígbà náà, Mugabe fi ẹ̀sùn kan lẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pé ó ń dá sí ọ̀rọ̀ Zimbabwe tí kò kàn wón.

Ṣùgbọ́n ní báyìí, Mnangagwa ní orílẹ̀ èdè náà kò lè máa dá gbé mọ́ o.