Ìjọba san N135m gbàmábínú fun ìdílé àwọn ti wọ́n pa ní Apo

Miniista fun Idajo
Àkọlé àwòrán,

Malami pín sọ̀wédowó fún àwọn ìdílé àwọn tí ó kú ní Abuja ní Ọjọ́bọ.

Ó pé ọdún márùń tí ikọ̀ ọmọ ogun Naijiria àti àwọn ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ kọlù àwọn kan.

Ikọlù yìí jẹ́ sí ilé àwọn aṣòfin tí wọn kò tíì parí ní Apo/Gudu, Abuja.

Ijọba àpapọ̀ ti san N135m owo gbà-má-bínú fún ídílé àwọn mẹ́jọ tó kú nínú ìkọlú náà.

Nínú ìkọlù náà tí ó ṣẹlẹ̀ ní oṣù kẹsàń odun 2013, yàtọ̀ sí àwọn tó kú, àwọn mọ́kànlá ni ò fara pa.

Mínísítà fún ìdájọ́ àti ọ̀rọ̀ ofin Mr. Abubakar Malami (SAN) ni ó pín sọ̀wédowó fún àwọn ìdílé àwọn tí ó kú náà ní Abuja ní Ọjọ́bọ.

Chidi Odinkalu, tó jẹ́ alága Ìgbìmọ ẹlẹ́ni mẹ́ta tí àjọ ajàfẹ́tọ́ gbé kalẹ̀ salaye nínú àbájáde rẹ̀ ní oṣù kẹrin ọdún 2014 pé ìjọba àpapọ́ ni ó ṣokùnfà ikú àwọn ẹni mẹ́jọ náà.

Àjọ náà ni ó tún sọ pé kí ìjọba san owó náà fún àwọn idílé àwọn tí ó kú.

Àwọn tí wọ́n ṣe 'kú pa nínú ìkọlù náà jẹ́ bíì ọmọ ọdún méjìdínlógún sí márùnlélógún.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: