Ẹbi yóò sèwádìí ohun tò pa Michael Adéyẹmọ

Micheal adeyemo Image copyright @Micadeyemo
Àkọlé àwòrán Kí ó tó kú, ẹkùn ìdìbò ìlà oòrùn Ìbàràpá ni aṣòfin Adeyẹmọ ṣojú fún

Àyẹ̀wò yóò wáyé lórí òkú Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, aṣofin Michael Adeyẹmọ tó dagbere fáyé lówúrọ̀ ọjọ́ ẹtì.

Iléèwòsàn ńlá UCH nílù Ìbàdàn ni àyẹ̀wò yii yoo ti waye.Ọ̀kan lára àwọn mọ̀lẹ́bí olóògbé náà kan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ rẹ̀ ló fi ọ̀rọ̀ yìí tó aṣojúkọ̀ròyìn BBC Yorùbá, Rótìmí Ọ̀kédáre létí nílùú Ìbàdàn.

Àkọlé àwòrán Ṣáájú iyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, òhun ni igbákejì akójánu ilé náà

Ó ní wọn pinnu ìgbésẹ̀ yìí láti mọ ohun gan an tó ṣokùnfà ikú rẹ̀.Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Aṣofin Michael Adeyẹmọ kú sí ilé ìwòsàn Jericho nílùú Ìbàdàn tí ìròyìn sì sọ pé àìsàn ọkàn ló paá.

Àkọlé àwòrán Páropáro ni ile olóògbé náà dá nígbàtí akọ̀ròyìn BBC Yorùbá de ilé rẹ̀

Páropáro ni ile olóògbé náà dá nígbàtí akọ̀ròyìn BBC Yorùbá de ilé rẹ̀ tó wà lágbègbè Agodi GRA nílùú Ìbàdàn.

Bákanáà ní wọ́n ti ṣí ìwé ìbánikẹ́dùn kan síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ilé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lórúkọ rẹ̀ .

Image copyright facebook/Rt Hon Michael Adeyemo
Àkọlé àwòrán Iléèwòsàn ńlá UCH nílùú Ìbàdàn ni àyẹ̀wò yii yoo sì ti waye

Kí ó tó kú, ẹkùn ìdìbò ìlà oòrùn Ìbàràpá ni aṣòfin Adeyẹmọ ṣojú fún.Ṣáájú iyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi olórí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, òhun ni igbákejì akójánu ilé náà.