Àwo tuntun tí Simi gbé jáde, 'Simisọ́lá' gbayì fún un láwùjọ́

Simi olorin Image copyright @The_Headies/iamsimi.com
Àkọlé àwòrán Simi gba àmì ẹ̀yẹ

Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí akọ̀ròyìn BBC Yorùbá se pẹ̀lú gbajúgbajà olórin ọmọ Nàìjíríà, Simisọla Bolatito Ogunleye, ó ní "bí èèyàn bá ń se ǹkan, láti ní ìtẹ́wọ́gbà àti ìbò tó pọ̀ jù ni..., èmi kò rí ìpènijà nínú ìdìje fún àmì ẹ̀yẹ̀ yìí, ìsinilọ́kàn lé wà sùgbọ́n ó tún jẹ́ ohun t'ééyàn n'ífẹ sí".

Ó fi kún un wípé "pẹ̀lú ìrétí, gbogbo ìsọ̀rí tó wà fún ìdíje yìí ni òun yóò ti gbégbá orókè".

Àkókó yìí fẹ́ dà bí ọ̀kan lára èyí tó dára jù nínú isẹ́ orin tí Simi ńse. Àwo tó sẹ̀sẹ̀ gbé jáde, Simisọla ló ti ńwa ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyì àti orúkọ fún un láwùjọ.

Ní lọ́ọ́lọ́ yìí ètò àmì ẹ̀yẹ X3M fún àwọn olórin ni Simi ti jáwe olúborí nínú ìdíje t'ọdún yìí fún àmì ẹ̀yẹ Headies èyí tí yóo wáyé nílu Èkó ní Ọjọ́ Kárun Osù Kárun ọdún 2018.

Pẹ̀lú ìpólówó àwọn mẹ́fà tí wọ́n yàn láti figagbága, Simi ló m'ókè jù nínú àwọn olórin náà tí àwọn míì tí wọ́n yàn kò sì ní tó ìbò.

Nínú àwọn àmúyẹ tí wọ́n fi yàn wọ́n ní obìnrin tóhún rẹ̀ jákè jù eléyìí tí wọ́n yan orin rẹ̀, 'Gone for Good' orin rẹ̀ tó gbilẹ̀ jù, Joromi ni wọ́n yàn fún àwo tí àgbéjáde rẹ̀ dára jù nígbàtí orin rẹ̀, 'Sinmisọ̀la' gbégbá orókè nínú ìsọ̀rí orin R&B tó yááyì jù àti àwo tó dára jù.

Bakan náà, orin ẹ̀ tó dá dúró jáde jù 'Smile for me' ni yóò figbagbága nínú ìdíje ìsọ̀rí orin R&B tó dá dúró jù.

Láfikún, orin t'óùn àti Adekunle jọ kọ, Gold's No Forget wà lára èyí tí wọ́n yàn lára ìsọ̀rí àwọn orin alájọsepọ̀. Bákan náà wọ́n yan ẹni tí wọ́n jọ fí òntẹ̀ lu orin wọn, Praiz nígbà méjì nínú ìdíje àmì ẹ̀yẹ náà. Wọn kò mú Praiz fún ti olórin àdákọ R&B tó dára jù bẹ́ẹ̀ sì ni wọn ò mú u nínú ìsọ̀rí àwọn olórin tí ohùn wọ́n jákè jù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oṣó ni mí, àjẹ̀ ni mí - Brymo

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObinrin lo mu mi fẹran orin kikọ - Patoranking
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMegabite: Ilé-ìwé ni mo ti bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ