NEC fi òfin de dída ẹran ọ̀sìn kiri nìpínlẹ̀ márùn uń

ọ̀pọ̀pọpọ̀ màálù àti darandaran kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Darandaran Nàìjíríà gbọ́dọ̀ kọ́ ọgbà fún ẹran ọ̀sìn wọn báyìí

NEC bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ wíwá ojútùú sí ìṣòro àwọn àgbẹ̀ àti àwọn darandaran pẹ̀lú òfin

Àwọn ìgbìmọ̀ alásẹ ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, NEC, fọwọ́ sí àbádòfin àwọn ìgbìmọ̀ tí ìjọba yàn láti wá ojútùú sí ìjà ojoojúmọ́ láárín àwọn àgbẹ̀ àti àwọn darandaran gbé wá.

NEC gbé òfin kalẹ̀ pé kí gbogbo darandaran kọ́ ọgbà fún àwọn ẹran ọ̀sìn wọn bẹ̀rẹ̀ láti ìpínlẹ̀ Benue, Taraba, Adamwa, Plateau àti Kaduna kì àláfíà lè jọba ní àwọn ẹkùn wọ̀nyìí.

Òpọ̀lọpọ̀ ìgbà ni ìjà ti wáyé tó já sí ikú àti òfò dúkìá.

Benue ní ìjọba ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ ni

Ogbẹ́ni Tever Akase, tó jẹ́ agbẹnusọ ìpínlẹ̀ Benue, ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀ pé ohun tó kù ni kí ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò pé kí wọ́n fi òfin náà múlẹ̀ bí ó ti yẹ káàkiri.

Báyìí, ẹnu ìpínlẹ̀ Benue ti gba ọ̀rọ̀ lórí òfin darandaran rẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionNEC fi òfin de dída ẹran ọ̀sìn kiri nìpínlẹ̀ márùn uń

NEC gbà pé ìgbẹ́sẹ̀ yìí yóò fòpin sí ìkọ̀lù àwón darandaran láti ilẹ̀ òkèèrè.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀìsàn ibà; Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa lílo ewé áti egbò