PDP: A fẹ́ gba odindin Imo padà ni lọdún tó n bọ

Asia ẹgbẹ́ òṣèlú People Democratic People Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán PDP kò gbàgbọ́ nínú ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ típínlẹ̀ Imo fẹ́ ṣe lóṣù keje ọdún yìí

Égbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) nipínlẹ̀ Imo ti ni ó ṣeéṣe kí ó má kópa nínú ètò ìdìbò tó m bọ̀

Ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keje ọdún yìí ni wọ́n ń pinnu kí ìdìbò fún yíyan alága ìjọba ìbílẹ̀ nípínlẹ̀ Imo wáyé.

Ọgbeni Damian Opara, tó jẹ̀ alukoro ẹgbẹ́ náà fún ipínlẹ̀ Imo, fi àtẹ̀jáde síta pé kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ fà sẹ́yìn nínú ètò ìdìbò náà

O ní ìgbésẹ̀ ìdìbò náà ti ń ni ǹkan míràn nínú, àfi ti àjọ elétò idìbò INEC bá gba àṣẹ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ pé kí wọn sún un síwájú.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionPDP: A fẹ́ gba odindin Imo padà ni lọdún tó m bọ

Ogbeni Deji Doherty tọ jẹ́ ọmọ ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ẹkùn ìwọ̀ oòrùn Naijiria ṣalaye ìpinnu ẹgbẹ́ PDP pé ìdìbò àpapọ̀ ló jẹ PDP lógún bayìí, kìí ṣe tìjoba ìbílẹ̀.

A kò tíì rì agbẹnusọ àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress bá sọ̀rọ̀ di ìsinyìí.