Àtíkù: Ọbásanjọ́ kìí se Ọlọ́run tó leè ní kí ń má di ààrẹ

Ọbásanjọ́ na ọwọ́ sí Àtíkù láti bọ̀ọ́ lọ́wọ́ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọjọ́ pẹ́ tí aáwọ̀ ti wà láàárín Ọbásanjọ́ àti Àtíkù

Igbákejì aarẹ tẹ́lẹ̀ ní Nàíjíríà, Àtíkù Abubakar ti kéde pé dandan kọ́ ni kí òun lọ fomí balẹ̀ ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà, kí òun tó leè di ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà.

Àtíkù kéde bẹ́ẹ̀ lásìkò tó ń bá BBC Hausa sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Sátidé nígbà tí wọn bií pé báwo ló se fẹ́ di ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà láì kọ́kọ́ se ẹ ń lẹ́ ń bẹ̀un sí Amẹ́ríkà.

Àtíkù wá ń bèèrè pé sé "òfin kankan wà tó ní dandan ẹni tó bá fẹ́ jẹ ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà gbọdọ̀ kàn sí Amẹ́ríkà ná, kí onítọ̀ún tó leè di ààrẹ?"

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àmọ́sá, Igbákejì aarẹ tẹ́lẹ̀ náà fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòtọ́ọ́ ni orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà kọ̀ láti fún òun ní ìwé àsẹ ìwọ̀lú wọn, nígbà tí òun bèèrè fún un.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Àtíkù Abubakar ti ń gbìnyànjú láti di ààrẹ Nàíjíríà

Sé Ọbásanjọ́ jẹ́ Ọlọ́run ni?

Bákan náà ni Àtíkù tún sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ kan tí ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olóyè Olúsẹ́gun Ọbásanjọ́ sọ pé níwọ̀n ìgbà tí òun Ọbásanjọ́ bá sì wà ní ayé, Àtíkù kò leè di ààrẹ́ orílẹ̀èdè Nàíjíríà. Àtíkù ní sé Ọbásanjọ́ jẹ́ Ọlọ́run ni? kódà òun kò se àìsùn kankan lórí ọ̀rọ̀ yìí.

'Tó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run ni kí ń di ààrẹ orílẹ̀èdè Nàíjíríà, kò sí ẹnikẹ́ni, tó fí mọ́ Ọbásanjọ́ tó leè pe Ọlárun ní ìjà."