Barcelona fàgbà han Deportivo láti gba ife ẹ̀yẹ

Andres Iniesta pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ̀ rẹ̀ ní ikọ̀ Barcelona Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Andres Iniesta gba ife ẹ̀yẹ La liga pẹ̀lú Barcelona fún ìgbà ìkẹyìn kó tó kúrò níbẹ̀

Ikò Barcelona gba ife ẹ̀yẹ La liga lẹ́yìn tí wọ́n f'àgbà han ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu Deportivo La Coruna pẹ̀lú àmìn ayò mẹ́rin sí méjì

.Àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lu n nì Lionel Messi ló gbá àmìn ayò mẹ́ta wọle, tí ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu náà fi jáwé olúborí nínú ìdíje náà.

Èyí ni ìgbà karùndínlọ́gbọ̀n tí ikò Barcelona yóò gba ife ẹ̀ye La liga.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu alátakò Real Madrid ní wọ́n ti gba àmin ẹ̀yẹ náà lẹ́ẹ̀mẹtàlélọ́gbọ̀n.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Messi fakọyọ pẹ̀lú àmìn ayò mẹ́ta nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tó wáyé láàrin Barcelona àti Deportivo

Ìgbà kẹrìndínlọ́gbọ̀n nìyí tí Messi yóò gbá àmìn ayò mẹ́ta wọle nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ kan ṣoṣo fún ikọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu tí o'ń sojú àti orílẹ́-èdè rẹ̀.

Related Topics