Adájọ́ rán agbẹjọ́rò àgbà lọ sẹ́wọ̀n oṣù kan

Joseph Nwobike Image copyright JNCLAWFIRM
Àkọlé àwòrán Nwobike ní òótọ́ ni òun fi ìfìwéránṣẹ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ náà

Ilé ẹjọ́ kan ní Ìpínlẹ̀ Èkó ti rán agbẹjọ́rò àgbà kan Joseph Nwobike lọ s'ẹ́wọ̀n oṣù kan lorí ẹ̀sùn pé ó fẹ́ yí da ojú òfin bolẹ̀.

Adájọ́ Raliat Adebiyi tí ó gbọ́ ẹjọ́ Nwobike, so pé àjọ tí ó ń kojú ìwà jẹgúdújẹrá tí a mọ̀ sí EFCC ti fi hàn dájúdájú pé agbẹjọ́rò àgbà náà bá àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ kan sọrọ̀ láti jẹ́ kí wọ́n máa gbé àwọn ẹjọ́ rẹ̀ lọ sí iwájú àwọn adájọ́ ti ó fẹ́.

EFCC fi ẹ̀sùn kan Nwobike pé ó fẹ́ fi owó ránṣẹ́ si adájọ́ àgbà méjì, Mohammed Yunusa ati Hyeladzira Nganjiwa, láti rí i pé wọ́n dá ẹjọ́ tí yóò tẹ lọ́rùn. Ṣùgbọ́n ó ní òun kò jẹ̀bi.

Ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ fi àwọn ìfìwéránṣẹ́ rẹ̀ pẹlú àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ méjì sọ̀rọ̀ déédé lórí ète yìí.

Nwobike ní òótọ́ ni òun fi ìfìwéránṣẹ́ náà ṣọwọ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ náà ṣùgbón kìí ṣe láti fẹ́ yí dà ojú òfin bolẹ̀.

Related Topics