NLC: Ìgbà kẹta rèé tẹ́gbẹ́ òsìsẹ́ yóò wàákò pẹ̀lú ìjọba lábẹ́ Wabba

Iwọde ẹgbẹ oṣiṣẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn gomina lawọn o le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira f'oṣiṣẹ

Ọjọ Kẹrinla, Osu Kẹrin,ọdun 2018 ni ẹgbẹ awọn osisẹ lorilẹede Naijiria yan Comrade Ayuba Wabba gẹgẹbi aarẹ ẹgbẹ naa.

Lati igba yii ni Ayuba Wabba gẹgẹbi adari ẹgbẹ ti bẹrẹ si ni kopa ninu igbesẹ fun agbelarugẹ awọn osisẹ ati fifi owo kun owo osu wọn lorilẹede Naijiria, eyi to n mu iyansẹlodi lọwọ nigba miran.

Irufẹ igbesẹ bẹẹ lo fẹ waye ni Ọjọ Kẹfa, Osu Kọkanla, Ọdun 2018, tawọn osisẹ si fẹ faraya pẹlu ijọba lati beere fun ẹkunwo sugbọn Wabba sọ fun awọn osisẹ to n mura lati da isẹ silẹ naa pe, eyi ko lee ri bẹẹ mọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Minimum wage: Àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ èrò wọn lórí ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́

Lara awọn ohun ti wọn si fi pẹtu sawọn osisẹ lọkan pe iyansẹlodi naa ko wulo mọ ni pe, igbimọ tijọba gbe kalẹ ati ẹgbẹ osisẹ yoo joko sepade, ti wọn yoo si fẹnu ọrọ jona.

Lẹyin ipade naa si ni wọn yoo polongo gbedeke owo osu osisẹ ni irọle Ọjọ Isẹgun, Osu Kọkanla, ọdun 2018.

Igba melo ni ẹgbẹ osisẹ ti gunle iyansẹlodi labẹ isakoso Ayuba Wabba?

  • Ogunjọ, Osu kọkanla, ọdun 2015 ni awọn osisẹ kọkọ bẹrẹ si ni faake kọri wi pe, awọn ko lee maa gba ẹgbẹrun mejidinlogun gẹgẹbi gbedeke owo osu awọn osisẹ.
  • Eyi waye lẹyin ti awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji pa ẹnu pọ wi pe, awọn ko ni lee san ẹgbẹrun mejidinlogun gẹgẹbi owo osu osisẹ to kere julọ losoosu.
  • Ni ọdun 2016, awọn osisẹ gunle iyansẹlodi ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Karun, ọdun naa, lẹyin ti ijọba fi owo kun owo epo lati Naira marundinlaadọrin si Naira mejidinlogoje.
  • Gbogbo ẹgbẹ olukọ Ile iwe Giga Fasiti ati awọn olukọ ile iwe lo parapọ lati kọ ekunwo owo epo bẹntiroolu naa.
  • Bakan naa, Ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC fẹ gunle iyanselodi ni Ọjọ Iṣẹgun, Osu Mọkanla, Osu 2018 lati beere fun afikun gbedeke owo oṣu osisẹ to kere julọ lati ẹgbẹrun mejidinlogun si ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.

Ẹgbẹ́ òṣiṣẹ́ Nàìjíríà so ìyanṣẹ́lódì rọ̀

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ti so iyanṣẹlodi to fẹ ẹ gun le l'ọjọ Iṣẹgun lati beere fun afikun owo oṣu rọ bayii.

Ẹgbẹ NLC sọ fun BBC pe wọn so iyanṣẹlodi naa rọ, lẹyin ti ijọba gbe igbimọ ẹlẹni mẹta kalẹ lati jiroro lori owo oṣu tuntun fun awọn oṣiṣẹ.

Àkọlé fídíò,

Lekan Kingkong: Níbikíbi tí mo bá wà, màá gbé àṣà Yorùbá ga

Aarẹ ẹgbẹ naa, Ayuba Wabba to kede ọrọ naa lalẹ ọjọ Aje sọ pe, igbesẹ ti ẹgbẹ oṣiṣẹ gbe waye lẹyin ti awọn ati ijọba fẹnuko, ti wọn si fi ọwọ si iwe adehun.

Bo tilẹ jẹ wipe Wabaa ko sọ iye ti ijọba gba lati san fun oṣiṣẹ, o sọ pe, ikede owo oṣu tuntun yoo waye lọjọ Iṣẹgun lẹyin ti igbimọ ẹlẹni mẹta naa ba gbe abọ iwadi rẹ fun Aarẹ Muhammadu Buhari.

Ẹgbẹ́ NLC n fẹ ki ijọba maa san ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira gẹgẹ bi owo oṣiṣẹ to kere ju lọ, ṣugbọn awọn gomina sọ pe awọn ko le san ju ẹgbẹrun mejilelogun.

Ìyanṣẹ́lódì ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ kò le fa ọ̀wọ́n epo - NNPC

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

NNPC sọ pe awọn to n lo ọkọ ati awọn to tun n lo eporọbi fun awọn nkan mi ko ni ohunkohun lati bẹru

Ileeṣẹ to n mojuto ipese epo rọbi ni Naijiria, National Petroleum Corporation, NNPC ti ni, ko si nkan to jọ pe epo bẹtiro yoo di ọwọn gogo ni orilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi sita lori ẹrọ ayelujara rẹ, Ọga agba ileeṣẹ NNPC lẹka ibaṣepọ araalu, Ọgbẹni Ndu Ughamadu, sọ pe ileeṣẹ naa ni epo rọbi toto lo fun ọjọ mọkandinlogoji, ati pe epo rọbi to wa nilẹ lọwọlọwọ, yoo to lo fun ọjọ mẹẹdọgbọn.

O sọ pe, awọn eeyan to n lo ọkọ ati awọn to tun n lo epo rọbi fun awọn nkan mii, ko ni ohunkohun lati bẹru nitori pe ileesẹ naa ni anito lati fun wọn ni ohun gbogbo ti wọn nilo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Ireti Yusuf: Ìsòro àti fẹjọ́ sùn ló ń mú kí ìwà ìfipábánilòpọ̀ gbilẹ̀ si

Agbẹnusọ ileeṣẹ NNPC ọhun sọ pe, ikede naa di dandan fun wọn lati ṣe nitori awuyewuye to n lọ kaakiri ilu pe, o sẹeṣe ki awọn eniyan ma ri epo ra jakejado Naijiria, nitori iyanṣẹlodi ti ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹ ẹ gun le.

Ughamadu wa gba awọn to n wa ọkọ lati maa ṣe ra epo pamọ, nitori pe, ileeṣẹ naa yoo ṣe gbogbo nkan to ba le ṣe lati ri i daju pe, iyanṣẹlodi naa ko ni ipa buruku lara bi wọn ṣe n pin epo kaakiri Naijiria.

O ni ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria maa kuna lati jẹ ki ileeṣẹ to n risi idiyele eporọbi, DPR, tabi awọn agbofinro, mọ nipa awọn ileepo to ba gbiyanju lati lo anfaani bi nkan ṣe ri l'orilẹede yii lati fi ara ni araalu

NUPENG ti ìyanṣẹ́lódì NLC lẹ́yìn

Iroyin kan ti sọ tẹlẹ pe, o ṣeéṣe kí adínkù bá epo bẹntiróòlù lọsẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ epo bẹntiróòlù àti afẹ́fẹ́ gáàsì, NUPENG ṣe fi àtìlẹ́yìn wọn hàn fún ẹgbk àpapọ̀ òṣìṣẹ́, NLC.

Ìjọba àpapọ̀ sì ti gba àṣẹ ilé ẹjọ́ látọ̀dọ̀ ilé ọjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilé iṣẹ́ lọ́jọ́ ẹtì láti dẹkun gígùn lé ìyanṣẹ́lódì àwọn òṣìṣẹ́.

Oríṣun àwòrán, Facebook/NLC

Àkọlé àwòrán,

NUPENG ti ìyanṣẹ́lódì NLC lẹ́yìn

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ oṣiṣẹ lapapọ lorilẹede Naijiria ti fi aake kọri wọn ni dandan laa, awọn yoo gun le iyanṣẹlodi miran lọjọ Iṣẹgun ti i ṣe ọjọ kẹfa oṣu kọkanla ti ijọba ba kọ lati maa san ọgbọn ẹgbẹrun naira gẹgẹ owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.

Nígbà tí wọ́n bí NUPENG bóyá wọn yóò dara pọ̀, èsì tí ààrẹ NUPENG Prince Akporeha fọ̀ ni pé "ṣé a ò kí ń ṣe ẹ̀ka àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ni? ṣé NUPENG dá wà ni? Dájú dájú a wà pẹ̀lú NLC.

Nígbà tí wọ́n rán an létí pé ìjọba àpapọ̀ mà ti gba àṣẹ ilé ẹjọ́ láti dá wọn lẹ́kun, ààrẹ NUPENG ní, "à ń retí àṣẹ".

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Awọn gomina lawọn o le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira f'oṣiṣẹ

Aarẹ ẹgbẹ oṣisẹ, NLC Ayuba Wabba ni ẹgbẹ naa ko mọ ohun kankan nipa aṣẹ ti ile-ẹjọ pa, bẹẹ ni awọn ko gba iwe kankan lati ile-ẹjọ.

Ọgbẹni Wabba fi kun ọrọ rẹ pe igbesẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ lapapọ nibi ipade ti wọn ṣe papọ loni ni lati gun le iyanṣẹlodi miran lọjọ Iṣẹgun.

Awọn gomina lawọn o le san ọgbọn ẹgbẹrun naira

Ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fesi si ọ̀rọ̀ ti awọn gomina sọ pe ''awọn ko le san ju ẹgbẹrun mejilelogun ati ẹẹdẹgbẹta Naira gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju.''

Oríṣun àwòrán, Facebook/NLC

Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sèwọ́de

Nibi ipade oniroyin kan to waye nilu Abuja ni awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ti fi ohun ṣọkan pe awọn naa ko le gba owo oṣu to ba din ni ọgbọ̀n ẹgbẹrun gẹgẹ bi owo oṣu to kere ju.''

Wọn fi kun ọrọ wọn pe ki awọn gomina pada si ipinlẹ kaluku wọn, lati lọ duna-dura pẹlu awọn oṣiṣẹ wọn, kiiṣe ipinnu ajumọṣe.''

Àkọlé àwòrán,

Ìyanṣẹ́lódì míràn ń kànlẹ̀kùn lẹ́yìn t'áwọn gómìnà sọ pé àwọn kò lè san ju #22,500 lọ fún 'Minimum wage.'

Ati wi pe ẹgbẹ́ awọn gomina ọhun, NGF, kiiṣe ẹgbẹ ti ofin da mọ, bikose ikorajọpọ awọn oloṣelu.''

Aarẹ ẹgbẹ NLC, Ayuba Wabba sọ nibi ipade naa pe ''ti awọn gomina ba fi kọ̀ lati san iye ti awọn n beere fun, ohunkohun ko ni i di iwọde ti awọn fẹ ẹ ṣe jakejado orilẹede Naijiria l'ọjọ kẹfa, oṣu Kọkanla, ọdun 2018.

Ṣaaju ni awọn gomina ipinlẹ mẹrindinlogoji lorilẹ-ede Naijiria kede pe awọn ko le san ju ẹgbẹrun mejilelogun ataabọ naira lọ gẹgẹ bi owo osu oṣiṣẹ to kere julọ lẹyin ipade pajawiri ti wọn ṣe lọjọ Iṣẹgun.

Àwọn gómìnà sọ fun ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lábẹ́ àbùradà NLC àti TUC pe àwọn kò lágbára láti san ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún tí wọn ń bèèrè fùn, bẹ́ẹ̀ni ìjọba àpapọ̀ náà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lohun lè san.

Àkọlé fídíò,

NLC: Àwọn olósèlú ń la títì láì sanwó osù torí owó tí wọn yóò rí lórí àkànse isẹ́

Èwẹ̀, alága ẹgbẹ́ àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lábẹ́ àbùradà NLC Ayuba Wabba sọ pé ó sàn kí àwọn gómìnà lọ tún ìpàdé wọn ṣe, bíbẹ́ẹ̀kọ́ àwọn yóò gùn lé ìyanṣẹ́lódì míràn ni ọ́jọ́ kẹfà, Oṣù Kọkànlá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣe ìwọ́de lọ́jọ́ Ìṣégun káàkiri orílẹ́èdè Nàìjírìa pe awọn ko ni gba din ni ọgbọn ẹgbẹrun náírà gẹ́gẹ́ bí owó oṣù òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ.

Àkọlé fídíò,

Omar Victor Diop: Ipa Áfíríkà nínú àkọsílẹ̀ ìwé kọja ògo tí wọ́n ń fún un lágbáyé

Ìwọ́de lórí ẹ̀kúnwó owó oṣù

ẹka ti ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti darapọ̀ mọ́ àwọn ojúgbà wọn káàkiri Nàìjíríà níbi ṣíṣe ìwọ́de láti fẹ̀hónú hàn lórí owó oṣù òṣìṣẹ́ tí ó kéré jù.

Ìwọ́de náà bẹ̀rẹ̀ láti ọ́ọ́fìsì àwọn ẹgbẹ́ ọ̀ṣìṣẹ́ ní agbègbè Yidi, lọ sí Gate àti Mọkọla nílú Ìbàdàn.Wọ́n késí ìjọba àpapọ̀ láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ owó oṣù òṣìṣẹ́ tí ó kéré jù.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Owó oṣù tuntun ọ̀hún nìrètí wà pé yóò gbérasọ l'óṣù Kẹjọ, ọdún 2018.

Wọ́n sì ṣe àlàyé pé ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n naira tí àjọ náà ń béérè fún kò tó láti gbọ́ bùkátà àwọn òṣìṣẹ́.Wọ́n fi kún ọ̀rọ̀ wọn pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà ni àwọn òṣìṣẹ́ ń kojú lórí àtijẹ-àtimu bó tilẹ̀ jẹ́ pé "àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣọ̀fin orílẹ̀-ede Nàìjíríà ló ń gbówó jùlọ l'ágbáyé.

Àkọlé àwòrán,

Awa naa n fẹ ẹkunwo owo oṣu

Ìwọdé naáà ń wáyé jákè-jádò àwọn ìpínlẹ̀ tó ń bẹ lórílẹ̀-èdè yìí láti kìlọ̀ fún ìjọba àpapọ̀ lórí ohun tí àwọn òṣìṣẹ́ ń bèèrè fún.Áwọn alákósó ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ náà ṣe àlàyé pé àwọn yóò gùnlé ìyanṣẹ́lódì aláìnígbèdéke láti ọjọ́ kẹfà, oṣù kọkànlá, odún yìí, bí ìjọba bá kọ̀ láti ṣe ohun ti wọ́n fẹ́.

"Kòsí iṣẹ́, kò sí owó" ni ìjọba sọ fún àwọn òṣìṣẹ́ tó ń gbèrò láti dá iṣẹ́ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀rí, sùgbọ́n níbáyìí, wọ́n ti dá ìjọba lóhùn wípé, "kò sí owó oṣù, kò sí ìbò".

Kí ló fàá tí owó oṣù tuntun fi ṣòro?

Ní ọdún 2011 ni wọn ṣe òfin pé ẹgbẹ̀rún méjìdínlógún naira ni yóò máà jẹ́ owó oṣù to kéré jù ní Nàìjíríà.

Ní ìgbà náà, wọ́n ń ra owó dola ní naira 155, sùgbọ́n ní bá yì dola kan ti di naira 363.

Eléyì jẹ́ díẹ̀ lára ìdí tí àwọn òṣìṣẹ fi ń jà fún fífi owó kún owó oṣù.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ lábẹ́ àbùradà NLC àti TUC ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ Ọyọ ń ṣe ìwọ́de láti fẹ̀hónú hàn lórí owó oṣù òṣìṣẹ́ tí ó kéré jù.

Sùgbọ́n ìjọ̀ba kọ̀ tíì pinnu lórí iye tí wọn yóò fi kún owó àwọn òṣìṣẹ́.

Láìpẹ́ yìí ni ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà lórílẹ̀-èdè Nàìíríà ti sọ wí pé àwọn kò tako fífi owó kún owó àwọn òsìsẹ́, àmọ́ àwọn kò ní owó láti san án ni.

Lẹ́yìn náà ni àwọn ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ sọ̀ fún ìjọba pé kí owó òṣù tuntun tí ìjọba ṣe ìlẹ́rí má yẹ̀.

Èrò àwọn gómìnà lórí ' minmum wage':

Alága ìgbìmọ̀ àwọn gómìnà náà tó jẹ́ gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara, Abdulaziz Yari fi èyí léde lásìkò tó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, lẹ́yìn ìpàdé tí wọ́n ṣe ní ìlú Abuja.

Yari ní àwọn gómìnà ṣetán láti ṣe àtìlẹyìn fún fífi owó kún owó osìsẹ́, àmọ́ kò sí owó tàbí ohun àlùmọ́nì tí wọ́n yóò fi san àfikún owó oṣù náà.

Àmọ́sá, ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ní Nàìjíríà ti f'ewé ọmọ mọ́ ìjọba àpapọ̀ létí láti máse jẹ́ kí ohunkóhun yẹ ṣíṣe ámúsẹ owó oṣù tuntun.

Owó oṣù tuntun ọ̀hún nìrètí wà pé yóò gbérasọ l'óṣù Kẹjọ ọdún 2018.

Ààrẹ ẹgbẹ́ nàá, Ayuba Wabba, fi ìkìlọ̀ nàá síta láìpẹ́ yìí lásìkò ìpàdé ìjíròrò t'ẹ́gbẹ́ nàá ṣe nílùú Abuja ní ìmúrasílẹ̀ fún ayẹyẹ ọjọ́ àwọn òṣìṣẹ́ fún ọdún 2018.

Wabba ní "Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò ri dájú pé ohunkóhun kò pagidínà àsìkò tí ìgbìmọ̀ tó wà fún ètò owó oṣù ní Nàìjíríà ti là kalẹ̀."

Ó fi kun pé "àwọn òṣìṣẹ́, tó n pèsè ọrọ̀, gbọdọ̀ rí ìtọ́jú tó péye gbà, pàápà bí owó ọjà ṣe gbẹ́nu s'ókè.

Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ nàá wá n bèérè fún sísọ owó oṣù wọn di ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta Naira.

Lẹ́yìn ìgbà náà ni àwọ̀n òṣìṣẹ́ yan ìṣẹ́ lódì fún ìgbà díè.

Wọ́n sì ń tún sọ wípé àwọn yóò sì padà da iṣẹ́ sílẹ̀ tí ìjọba kọ̀ bá gbé owó oṣù tuntun jáde.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: