Fídíò codeine: Iléesẹ́ Emzor gba‘sẹ́ lọ́wọ́ òsìsẹ́

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionFídíò òògùn ikọ́ Codeine: Àpọ̀jù rẹ̀ ń ya ọ̀dọ́ ní wèrè

Fídíò lórí títà àti rírà oògùn ikọ́ olómi Codeine tí BBC fi síta ti ń bí oríṣíiríṣíi èrò láàrin àwọn ọmọ Nàìjíríà.

Èyí ni wọn fi tún ṣàfihàn èso burúkú tó ń bí láyé àwọn ọ̀dọ́ tó ń muú, pàápàá jùlọ, lẹ́kùn àríwá Nàìjíríà.

Emzor gbọnmú lóríi fídíò codeine

Àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ Emzor, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ tó ń se òògùn ikọ́ olómi tó ní èròjà codeine síta, fi sí orí ìkànnì twitter wọn ní @emzornigeria pé, wọ́n ti fòpin sí pínpín oògùn ikọ́ olómi Codeine síta báyìí títí wọn yóò fi parí ìwádìí abẹ́lé tí wọ́n n ṣe.

Bákan náà ni Iléeṣẹ́ Emzor ti dá òsìsẹ́ wọn tó ń pín èròjà náà dúró.

Wọ́n tún ní kí àwọn òṣìṣẹ́ méjì míràn lọ rọọ́kún níle ná.

Aisha Buhari gbarata lórí fídíò Codeine

Aya aàrẹ Nàìjíríà, Aisha Buhari lórí instagram @aishambuhari, ti ké gbàjàrè sí àwọn òṣìṣẹ́ elétò ààbò, àwọn iléeṣẹ́ apoogùn, olùkọ́, alágbàtọ́, òbí, alájọgbélépọ̀ àti àwọn aṣòfin Nàìjíríà láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ́lú ìjọba ja ogun yíì lájàyè.

Èrò àwọn ọmọ Nàìjíríàyapa lóríi fídíò codeine

Mairo Mandara, nínú ìkànnì twitter rẹ̀ @Drmairomandara, sọ̀rọ̀ pé, kí ìjọba fòfin de ṣíṣe oògùn ikọ́ olómi Codeine lọ́dọ̀ àwọn iléeṣẹ́ tọ́rọ̀ kàn, bíi Emzor Pharmaceuticals, Bioraj Pharmaceuticals àti Peace Standard Pharmaceuticals

Nínú èrò ti Politbru ni ìkànnì twitter @Politbru, ní, ìsẹ̀lẹ̀ yìí ti ń ní ọwọ́ kan ẹlẹ́yàmẹ̀yà nínú. Ó bèèrè pé, Ìran Ìgbò nìkan ní ojú wà lára rẹ̀ láti ìgbà tí olùkọni kan láti fásitì Bayero ni àríwá Nàìjíríà ti fẹ̀sùn kan àwọn olókowò Igbò pé àwọn ni wọn ń pín Codeine.

Charles the first, ni ìkànnì twitter @9jaBloke ní, kí Codeine to dé ni àwọn ènìyàn kan ti ń fín ṣáláńgá símú bẹ́ẹ̀ iléeṣẹ́ Emzor ni à ń pariwo rẹ̀

NT IPOB AK47 Carrier ni ìkànnì twitter @idmann_mit gbà pé, tí ìjọba kò bá tètè dí àlàfo ti Codeine ti wọn kó nílẹ̀ yìí, ojú awọn tó ń lòó máa ṣí sí lílo ǹkan míràn ni. Ó ní kí ìjọba gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ ní kíákíá

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: