Afénifẹ́re: Oníkálukú ni yóò tẹ̀ka síbi tó wù ú tó bá yá

Odumakin ati Adebanjo Image copyright YOUTUBE
Àkọlé àwòrán Odumakin àti Adebanjo: Àwọn Ọba kàn ń sọ tẹnu wọn ni o

Ẹgbẹ Afénifẹ́re ṣe lòdì sí ọ̀rọ̀ àwọn Ọba ilẹ Yoruba kan.

Oloye Ayo Adebanjo ati agbẹnusọ fun Afénifẹ́re, Yinka Odumakin, sọ fun BBC pe awọn Ọba ode oni ń beru ijọba ni wọn ṣe n sọrọ atileyin fun Buhari lọdun 2019.

Wón ni ko sẹni tó lè tọ́ka ibi tí awọn Yoruba yoo fì sí ni idibo 2019 nitori pe kò si ìkókó mọ́ nínú oludibo.

Ọ̀rọ̀ yii jẹyọ latari ọ̀rọ̀ Oba Ilu Eko, Ọba Rilwan Akiolu, ni ọjọ Ajé pe, ki awọn Naijiria ti Aarẹ Buhari lẹyin fun saa keji.

Ọ̀sẹ̀ melo kan sẹhin ni Alake ti Ilẹ Ẹgba, Oba Adedotun Gbadebo, naa sọ pe oun fara mọ ki Buhari gbe igba ibo fun saa keji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Oloye Ayo Adebanjo so pé, "Ka to gb'ominira, awọn Ọba kíi lọwọ ninu ọrọ̀ idibo.

Ipo Ọba laye atijọ maa n fi ógbón agba tọni sọna ni, ṣugbón ko ri bẹẹ mọ laye ode oni to jẹ pe, ti wọn ko ba ṣe ti ijọba to wa lode, ijọba le fiya jẹ wọn.

"Awọn Ọba to n s'atilẹhin fun Buhari ko fi ohun ti awọn ọmọ ilẹ Yoruba fẹ han. Ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ko mu'na doko l'ọdọ awọn eeyan rara."

O wa rọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba ki wọn lọ gba kaadi idibo wọn. O ni eyi lo maa fun wọn ni agbara lati yan eni ti wọn fẹ sipo to ba wu wọn.

Ninu ọrọ rẹ, Odumakin ni, "Ni ọdun 2015, Buhari da bi angeli, t'o n bọ wa yi gbogbo wahala Naijiria pada, ti ẹ ba wo ibo ti wọn di ni ilẹ Yoruba, Buhari ni ida mejilelaadota ibo, nigba ti, aarẹ ana Goodluck Jonathan, ni mejidinlaadota, ká má ṣẹṣẹ wa sọ isinyi. Enikeni ti o ba n sọ pe Buhari n bọ leekeji, ó n tan ara re jẹ pata ni."