Òṣiṣẹ́ Emzor tó ta Codeine fun BBC ti bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá

Chukwunonye Madubuike

Oríṣun àwòrán, Police

Àkọlé àwòrán,

Codeine:Ọwọ́ ba òsìṣẹ́ Emzor

Ọwọ́ tí ba òsìṣẹ́ Emzor tẹ́lẹ̀ rí Chukwunonye Madubuike tó ta òògún ikọ́ olómí ọmọdẹ́, codeine fún ìkọ̀ BBC tó ṣe ìwádìí bònkẹ́lẹ́.

Agbẹ́nusọ fún àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekó, Chike Otu tó bá BBC sọ̀rọ̀ sàlàyé pé wọn gbá a mú lásìkò tó ń ta òògùn tí ìjọba ti fòntẹ̀ dè tó sì ti lòdì sófin.

Ó sàlàyé pé òsìṣẹ́ Emzor tẹ́lẹ̀rì ni Madubuike tó sì ń ta òògùn náà lọ́nà àìtọ́ nítori pé ó lẹ́tọ̀ọ́ si láti ilé iṣẹ́.

Àkọlé fídíò,

Fídíò òògùn ikọ́ Codeine: Ó dùn lóòtọ́ àmọ́ ewu ni

O ní bótilẹ̀ jé pé ó yẹ kí o tàá fún àwọn tó tí gba ìwé àṣẹ láti ta irú ǹkan bẹ́ẹ̀ tí wọn sì ní ilé ìtajà òògùn ló yẹ kí ó máà tàá fún, sùgbọn ó bẹ̀rẹ̀ sí ní tàá fún àwọn ti wọn o ma ṣìí òògùn náà lò.

Agbẹ́nusọ fún àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekó ní ọwọ́ àwọn agbófinró bàá ní òsẹ̀ tó kọjá ní Ìdí Ìrókò lásìkò tó ń gbìyànjú láti sá kúrò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ sí orílẹ̀-èdè Benin Republic

Oti sàlaàyé pé àwọn ó ni pẹ́ gbé lọ sí ilé ẹjọ́.

Codeine: Ijọba àpapọ̀, ilé ìgbìmọ̀ aṣofin gbé ìgbésẹ̀ akin

Oríṣun àwòrán, Frankieleon

Àkọlé àwòrán,

òpin dé bá lílo oògùn ikọ́ olómi Codeine àti Tramadol

Ijọba àpapọ̀ fòfin de títà àti rírà tramadol àti oògùn ikọ́ olómi to ni codeine

Lẹ́yìn ti BBC gbe fidio jade ti o fi ṣàfihàn ewu ńlá to wa ninu mímu àpọ̀jù iru oògùn ikọ́ báyìí ni òfin jáde lórí rẹ̀.

Minisita fun Ọrọ Ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewole, sọ ni Abuja ni ọjọ Ẹtì, wi pe, oun ti fun ajọ ti ó ń gbogun ti ilokulo oògùn, ti a mọ si NAFDAC, ni àṣe lati ri i pe wọn kò fun ẹnikẹni ni iwe aṣẹ lati gbe oògùn naa wọle lati awọn orile-ede miran mọ́.

Oni oun gbe igbesẹ naa latari ilokulo oògùn ikọ́ ti o ni codeine ninu ni orile-ede yii.

Minisita naa ni, "A ṣe ipade pàjáwìrì pẹlu ajo ti ó ń ṣakoso oògun pípò ni orilẹ-ede yii ati NAFDAC, lati gba awọn oogun ikọ oni codeine pada kaakiri.

A tun ti pe ẹgbẹ awọn apoògun lati sọ fun wọn pe, a ti gbẹ́sẹ̀ lé awón oògùn naa.

Gbogbo awọn ajọ ti o nii ṣe pelu ọrọ yii ni a ti rọ lati foju sìta lori Codeine,Tramadol ati awọn oogun bẹẹbẹe.

Bakan naa, olori Ile Igbimo Asofin agba, Bukola Saraki, ti gboriyin fun BBC, fun fidio lori codeine naa, ninu agbejade kan ti agbenuso re fi ṣọwọ s'awọn oniroyin.

Saraki ni, ó fihan pe, Naijiria ni lati fọwọ́ líle mu ọrọ aṣilo oògùn bayii.

Saraki ni tori ọrọ yi ni Ile Igbimọ Aṣofin agba ṣe kó awọn ti ọrọ naa kan jọ ni Ipinle Kano ni osu Kejila odun 2017.

O ni, "Bi o ti lẹ jẹ pe mo ti n ṣiṣẹ lori ọrọ yii lati bii oṣu melo kan sẹyin, fidio BBC naa jẹ ki ọrọ naa wa ye mi daradara sii.

Bi a ba ka'wọ gbera, ọrọ yii ko le lójútùú. Gbogbo wa ni ọrọ yi kan."

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Saraki: Gbogbo wa ni ọ̀rọ̀ yíì kán báyìí

Sẹnetọ naa ni Ile Igbimo Asofin yoo gbe ofin jade lati kápá aṣilo oogun ni orilẹ-ede yi, pẹlu ofin miran ti yoo ṣetò iwosan fun awọn ti aṣilo oogun ti ya ni were sẹyin.

Lori ọrọ Codeine yi, aya aarẹ orile-ede yii ni ọrọ naa ba ni lẹru gan an ni gẹgẹ bi obi.

Oríṣun àwòrán, Aishabuhari

Àkọlé àwòrán,

Aisha Buhari: ọ̀rọ̀ yìí kọnilóminú púpọ̀

Aisha Buhari sọ ninu atẹjade kan lori Instagram pe ki awọn agbofinro, aṣofin ati awọn tí o n ṣe oogun sọ ọrọ naa di ija ti awọn funra wọn yoo ja lati dẹkun ilokulo oogun.

Ẹ wo fidio naa nibi:

Àkọlé fídíò,

Fídíò òògùn ikọ́ Codeine: Àpọ̀jù rẹ̀ ń ya ọ̀dọ́ ní wèrè

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: