Koko iroyin: Ìgbésẹ̀ ìjọba l'órí Codeine, ìkọlù NURTW níbi ayẹyẹ ọjọ́ òṣìṣẹ́
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Codeine: Ijọba àpapọ̀ fòfin de oògùn ikọ́ tó ń dorí àwọn ọ̀dọ́ rú
Oríṣun àwòrán, Frankieleon
òpin dé bá lílo oògùn ikọ́ olómi Codeine àti Tramadol
Ijọba àpapọ̀ f'òfin de títà àti rírà oògùn ikọ́ olómi to ni codeine lẹ́yìn ti BBC gbe fidio jade ti o fi ṣàfihàn ewu ńlá to wa ninu mímu àpọ̀jù iru oògùn ikọ́ báyìí.
Minisita fun Ọrọ Ilera, Ọjọgbọn Isaac Adewole, sọ ni Abuja ni ọjọ Ẹtì, wi pe, oun ti fun ajọ ti ó ń gbogun ti ilokulo oògùn, ti a mọ si NAFDAC, ni àṣe lati ri i pe wọn kò fun ẹnikẹni ni iwe aṣẹ lati gbe oògùn naa wọle lati awọn orile-ede miran mọ́.
Afẹ́nifére: Àwọn Ọba kò lè júwe ìdìbò 2019
Oríṣun àwòrán, YOUTUBE
Odumakin àti Adebanjo: Àwọn Ọba kàn ń sọ tẹnu wọn ni o
Ẹgbẹ Afénifẹ́re ṣe lòdì sí ọ̀rọ̀ àwọn Ọba ilẹ Yoruba kan.
Oloye Ayo Adebanjo ati agbẹnusọ Afénifẹ́re, Yinka Odumakin Adebanjo, sọ fun BBC pe awọn Ọba ode oni ń beru ijọba ni wọn ṣe n sọrọ atileyin fun Buhari lọdun 2019.
Wón ni ko sẹni tó lè tọ́ka ibi tí awọn Yoruba yoo fì sí ni idibo 2019 nitori pe kò si ìkókó mọ́ nínú oludibo.
Ọ̀rọ̀ yii jẹyọ latari ọ̀rọ̀ Oba Ilu Eko, Ọba Rilwan Akiolu, ni ọjọ Ajé pe, ki awọn Naijiria ti Aarẹ Buhari lẹyin fun saa keji.
Àarẹ ilẹ̀ Amẹrika Donald Trump, ti sọ pé ìṣekúpa àwọn ọmọlẹ́yìn Krístì nílẹ̀ Nàíjírià gbódọ̀ dópin.
Trump sọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń gbàlejò akẹgbẹ́ẹ rẹ̀ láti Nàíjíríà, Àarẹ Muhammadu Buhari nílé ìjọba Amẹ́rika, White House.
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun toni
NURTW da ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ òṣìṣẹ́ rú l'Ékó.
Àyájọ́ òṣìṣẹ́: NURTW gba ẹ̀jẹ̀ lára àwọn òsìsẹ