Ìdíje Champions league: Tani yóò tẹ̀síwájú láàárín Roma àti Liverpool?

Idanimọ Roma and Liverpool Image copyright @ChampionsLeague
Àkọlé àwòrán Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ ìpele yìí ti wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Roma àti Liverpool yóò kojú arawọn ni ìlú Róòmù lọ́jọ́rú láti leè mọ ẹni tí yóò tèsíwájú sí ìpele àsekágbá ìdíje Champions league ilẹ̀ Yúrópù.

Ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ ìpele yìí ti wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá níbití ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool ti fi àgbà han Roma pẹ̀lú àmì ayò márún sí méjì.

Pàtàkì ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà

Image copyright Liverpool FC
Àkọlé àwòrán Ìlú Romu ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool ti gba ife ẹ̀yẹ yìí

Ohun tí ó ń mú kí àwọn èèyàn ó máa pọ́n ẹnu lá de ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ni bí Roma ṣe yí ojú àwo padà fún Barcelona, lẹ́yìn tí Barcelona ti kọ́kọ́ ní àmì ayò Mẹ́ta sí òdo ni ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn àkọ́kọ́ ni Camp nou.

Ohun míràn tún ní pé, ní ìlú Romu yí ni èèkàn agbábọ́ọ̀lù Liverpool ni, Mohammed Salah ti gba bọ́ọ̀lù gbayì kí ó tó gba ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ níbi tí ó ti wá di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ fún àwọn alátakò báyìí.

Ohun mìíràn ni pe, ní ìlú Romu ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù Liverpool ti gba ife ẹ̀yẹ yìí lọ́dun 1984.

"Ṣé yóò bọ́sii tàbí kò ní bọ́ síi ?" ni ìbéèrè tó gba ẹnu àwọn olólùfẹ́ ẹ ikọ̀ méjèèjì yí báyìí ṣùgbọ́n ohun kan tó dájú ni pé Real Madrid ni èyí kéyí ikọ̀ tó bá borí nínú àwọn méjèèjì yóò máa pàdé ni àṣekágbá.

Kíni àwọn olùkọ́ni ikọ̀ méjèjì sọ?

Image copyright Liverpool FC
Àkọlé àwòrán Real Madrid ni èyí kéyí ikọ̀ tó bá borí nínú Roma ati Liverpool yóò máa pàdé ni àṣekágbá

Lójú olùkọ́ni ìkọ Liverpool, Jorgen Klopp, kò sí èyíkéyìí nínú àwọn ikọ̀ méjèèjì yìí tí kò tọ́ sí láti wọ ìpele àṣekágbá.

"Bí a bá leè rí èsì tí a bá fẹ́ níbí, ó tọ́ sí wa láti dé ìpele àṣekágbá. Tó bá sì jẹ́ pé Roma ni, ó tọ́ sí àwọn náà pẹ̀lú."

Image copyright Roma FC
Àkọlé àwòrán Olùkọ́ni Roma, Eusebio di Francesco ní ìrètí òun ni pé, ìyanu tó wáyé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Barcelona yóò tún wáyé

Olùkọ́ni Roma, Eusebio di Francesco ní ìrètí òun ni pé, ìyanu tó wáyé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ wọn pẹ̀lú Barcelona yóò tún wáyé.

"A kìí sába ń fún àwọn alátakò láǹfààní àti gbá bọ́ọ̀lù wọ àwọn wa.

A dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ wa, àtìlẹ́yìn wọn ṣe pataki fun wa."

Àwọn tí kò ni kópa

Image copyright @ChampionsLeague
Àkọlé àwòrán Agbabọọlu ikọ mejeeji ni wọn ti sese ti ko si ni kopa

Àwọn agbábọ́ọ̀lù márún nínú ìkọ̀ Liverpool ni kò ní kópa nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ tòní.

Àkọ́kọ́ ni Alex Oxlade-Chamberlain tí ó ṣeṣe ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

Adam Lallana, Emre Can ati Joel Matip pẹ̀lú kò ní kópa.

Roma pẹ̀lú yóò pàdánù Diego Perotti àti Kevin Strootman nítorí pé wọ́n ṣeṣe.