Iléeṣẹ́ ológun: ilé làbọ̀ ìsinmi oko láìpẹ́ f'Aṣàtìpó

Àwọn obinrin kan n ṣafihan tomati, erè oko wọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ológun ní ìgbésẹ náà yóò ṣilẹkun fún ìdápadà ọrọ ajé lágbègbè tí ọ̀rọ̀ kàn

Àwọn èèyàn tí làáṣìgbò ìdúnkoòkò-mọ́ni lé kúrò nílé káàkiri àwọn agbègbè kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò padà sí ìlú àti ilé wọn láìpẹ́.

Iléeṣẹ́ ológun oríilẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà, ní gbogbo ipá ni wọ́n ti ń sà báyìí láti ríi pé àwọn èèyàn náà padà sí ìgbé ayé wọn, pàápàá jùlọ àwọn tó wá láti agbègbè adágún odò Chad.Iléeṣẹ́ ológun oríilẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní èyí yoo lè jẹ́ kí ètò káràkátà níbẹ̀ dìde padà.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ológun ní gbogbo ipá ni wọ́n ń sà báyìí láti dá àwọn èèyàn náà padà sí ìgbé ayé wọn

Tukur Yusuf Buratai, to jẹ́ ọ̀gágun àgbà iléeṣẹ́ ọmọogun oríilẹ̀, ní òun àti olórí ẹ̀ka àjọṣepọ̀ ará ìlú, Nuhu Angbazo, pẹ̀lú olórí ikọ̀ ọmọogun tó ń rísí ọ̀rọ̀ ààbò ní ẹkùn ìlà oòrùn àríwá Nàìjíríà, 'operation LAFIYA DOLE' ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ lílọ sí àwọn agbègbè ni ìpínlè Yobe àti Borno.

Bakan naa ni wọ́n ti pè fún àtìlẹ́yìn àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ méjèèjì.Iléeṣẹ́ ológun ní ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbékalẹ̀ yìí tí wọ́n dà pè ni 'operation LAST HOLD' yóò yẹ̀ ọ̀nà fún ìdápadà iṣẹ́ ẹja pípa, iṣẹ́ àgbẹ̀ àtàwọn iṣẹ́ ọrọ ajé lágbègbè adágún odò Chad.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: