Àwón akẹ́kọ̀ọ́ há sínú Ṣáláńgá tó wó nílé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀

Ṣáláńgá Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ṣáláńgá ibi ìgbọ̀nsẹ̀ tó lè di pósí bí a kò bá ṣọ́ra

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé sáà ètò ẹ̀kọ́ tuntun ni Kenya, ni Ṣáláńgá wó nílé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kisulisuli, ti ẹkun Nakuru, ni orílẹ̀-èdè Kenya, tí àwon akẹ́kọ̀ọ́ sì há sinu rẹ̀.

Bíi aago mẹ́jọ̀ owuro niroyin gba igboro kàn pe àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti há sínú Ṣáláńgá tó dàwó nílé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kisulisu náà.

Awọn òbí àti alágbàtọ́ sáre darapọ̀ mọ́ àwón olùránlọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì lati dóòlà ẹ̀mí àwón akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún.

Tẹ́lẹ̀ wón kò mọ̀ iye àwón akẹ́kọ̀ọ́ to rì síbẹ̀, ṣugbón bayii, ọ̀ga àgbà ílé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kisulisu fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n ti ri gbogbo áwọn akẹ́kọ̀ọ́ mefeefa náà yọ tán.

Ṣáláńgá meedogbon ló dàwó nìlé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kisulisuli yìí lataari àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjò tó ń rọ̀ lati ǹkan bii ọ̀sẹ̀ merin seyin ni Kenya, ṣugbon ko si ẹni tó farapa.

Ilé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kisulisuli, lo tobi ju ni ìwọ̀ oòrùn Kenya ni Bungoma.

Ó tó akẹ́kọ̀ọ́ 3,500 to wà nílé ìwé alákọ́bẹ̀rẹ̀ Kisulisuli.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: