Òndó: Ọ̀gá àgbà àjọ ẹ̀ṣọ́-aláàbò ojúupópó (FRSC) dolóògbé

Ọ̀gbẹ́ni Vincent Jack Image copyright @FRSC AKURE/ FACEBOOK
Àkọlé àwòrán Ọ̀gbẹ́ni Jack jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́.

Ọ̀gbẹ́ni Vincent Jack, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà àjọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojúupópó (FRSC) ní ìpínlẹ̀ Òndó ti jáde láyé.

Ọ̀gbẹ́ni Vincent Jack, "papòdà lẹ́yìn tó ti wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn, èyí tó mú kó ma lè ṣiṣẹ́ rẹ̀ daadaa fún ìgbà díẹ̀."

Image copyright FRSC/ TWITTER
Àkọlé àwòrán Ọ̀gá àgbà àjọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojúpópó (FRSC) ní ìpínlẹ̀ Òndó ti jáde láyé

Adarí ẹ̀ka ìsẹ́ nínú àjọ nàá ní ìpínlẹ̀ Òndó, Ọ̀gbẹ́ni Oluṣẹ́gun Ògúngbémidé sọ fún BBC pé Ọ̀gbẹ́ni Jack jáde láyé lóòrọ̀ kùtù ọjọ́ kejì, oṣù Karùn, lẹ́yìn àìsàn ránpẹ́.

Ó ní ọjọ́ orí olóògbè n bẹ láàrin àádọ́ta ọdún sí ọgọ́ta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: