Ìjọba Nàíjíríà leè kógbáwọlé nítorí áíbuwọ́ lu àbà ìṣúná ọdún 2018

Buhari gbe aba kalẹ niwaju awọn aṣofin Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àìbuwọ́lu àbà ìṣúná ọdún 2018 ti ń kọ àwọn òǹwòye lóminú

O ṣeéṣe kí ìjọba orílẹ̀èdè Nàíjíríà ó paná bí wọn kò bá buwọ́ lu àbà ìṣúná ọdún 2018 kí ó tó di oṣù kẹfà.

Àwọn onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé tí wọ́n bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lóríi pípẹ́ tí ìgbésẹ̀ láti buwọ́ lu àbà ìṣúná ń pẹ́.

Wọ́n ní ìpalára kékeré kọ́ ni èyí ń ṣe fun ètò ọrọ̀ ajé pàápàá ìdókoòwò láti òkè òkun àti ìpèsè iṣẹ́.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìpalára tí àìbuwọ́lu àbà ìṣúná ń ṣe fún ìpèsè iṣẹ́ kò kéré

Ọ̀gbẹ́ni Túndé Ọlátúnjí ní 'yóò ṣe àkóbá fún àwọn tó fẹ́ dókòwò láti òkè òkun àti ìpèsè iṣẹ́.'

"Lóòótọ́ ko ṣẹlẹ̀ rí ṣùgbọ́n bí wọn kò bá buwọ́ lù ú kí oṣù kàrún tó parí, nígbà tí a bá wọ oṣù kẹfà, o ṣeéṣe kí wọ́n tilẹ̀kùn ìjọba."

O ní àwọn ẹ̀ka ọrọ̀ ajé bíi àkànṣe iṣẹ́, ìlàkalẹ̀ ètò ìṣèjọba, àti ìpèsè adùn ìjọba fáráàlú.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ní oṣù kọkànlá ọdún 2017 ni Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí̀ gbé àbá ìṣúná ọdún 2018 síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀

Ní oṣù kọkànlá ọdún 2017 ni Ààrẹ Mùhámádù Bùhárí̀ gbé àbá ìṣúná ọdún 2018 síwájú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀, sùgbọ́n títí di akoko yìí kò tíì sí àṣeyọrí kan lórí rẹ̀.

Onírúurú àwáwí àti ẹsùn ni ẹ̀ka ìjọba ń kéde lórí ìdì tí kò fi tíì bọ́ síi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: